Naijiria gbe ile-ẹkọ giga fasiti ti Alabama re ile-ẹjọ

Image copyright ALABAMA STATE UNIVERSITY
Àkọlé àwòrán Ile-ẹkọ naa sọwipe awọn jẹ ijọba orilẹede Naijiria ni $202,000

Ijọba orilẹede Naijiria n gbe ile-iwe giga fasiti Alabama State University lọ si ile-ẹjọ pẹlu ẹsun wipe wọn si owo iranwọ awọn akẹẹkọ wọn lọ.

Ijọba naa sọ wipe owo naa wa fun ile-gbigbẹ, iwe ati ounjẹ.

Ijọba naa pẹlu ọgọọrọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria to jẹ akẹẹkọ, ti buwọlu ẹjọ ti wọn pe lori ẹsun ti wọn fi kan ile-iwe giga fasiti ti Alabama, lati ọdun 2016.

Wọn fẹsun kan ile-iwe giga fasiti to wa fun awọn eniyan dudu, wipe wọn n gba ọgọọrọ owo ile gbigbe ati owo kilaasi ti wọn ko lo.

Ile-ẹkọ giga fasiti ti Alabama ninu idahun rẹ, sọwipe awọn ko se ikankan to buru, atiwipe awọn tẹle gbogbo asẹ ati adehun pẹlu ijọba orilẹede Naijiria.

Ile-ẹkọ naa sọwipe lootọ ni awọn jẹ ijọba orilẹede Naijiria ni ẹgbẹrun lona mejilerugba owo okeere, $202,000, lẹyin ti wọn san gbogbo owo tan, sugbọ awọn ti fi owo naa si apo iṣuna kan ni ile ifowopamọsi.

Amọ, asoju fun awọn akẹẹkọ naa, Anthony Ifediba sọ wipe oseese ki fasiti Alabama o jẹ ijọba Naijiria ni iye owo toto ẹgbẹrunlọnaẹgbẹrin owo okeere, $800,000.