Inec: Ọjọ idibo lati 2019 si 2055 ti wa l‘akọọlẹ

Image copyright @inecnigeria
Àkọlé àwòrán Idibo ọdun 2019 yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, osu Keji ati ojo keji, osu Kẹta, ọdun kan naa.

Ajọ to n risi eto idibo lorilẹede Naijiria, Inec ti kede ọjọ idibo gbogbo-gboo lati ọdun 2019 si 2055.

Ọjọ idibo gbogbo-gboo tọdun 2019 yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, osu keji ati ojo keji, osu kẹta odun to n bọ

Alaga ajọ Inec, Ọjọgbọn Mamood Yakubu lo se ikede yii nigba to n sepade pẹlu awọn adari ẹgbẹ oselu to wa lorilẹede Naijiria.

Ninu ọrọ rẹ, idibo tọdun 2019 yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, osu keji ati ojo keji, osu kẹta, ọdun kan naa.

Bakan naa lọdun 2023, idibo yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, osu keji ati ojo kẹrin, osu kẹta, ọdun naa.

Ni 2027, ọjọ̀ idibo naa ni ogunjọ,osu Keji ati ojo kẹfa, osu Kẹta, ni 2031, o ma waye ni ọjọ karundinlogun, osu Keji ati ọjọ kini osu Kẹta.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ajọ Inec ni ipolongo ọjọ idibo saaju ọdun naa yoo mu idagbasoke ba eto oselu lorilẹede Naijria

Lọdun 2035, ojo kẹtadinlogun, osu Keji ati ojo kẹta, osu Kẹta ni yoo waye: pẹlu ọjọ kọkandinlogun, osu Keji ati ọjọ karun, osu Kẹta, ọdun 2039.

Bakan naa, lọdun 2043, idibo yoo waye lọjọ kokanlelogun, osu Keji ati ọjọ keje, osu Kẹta ninu ọdun naa. Ti 2047 yoo waye lọjọ karundinlogun, osu Keji ati ojo keji, osu Kẹta.

Ọjọ idibo gbogboogbo ti ọdun 2051 ati tọdun 2055 yoo waye ni ọjọ kejidinlogun ninu osu Keji ati ọjọ keji osu Kẹta, pẹlu ogunjọ, osu Keji ati ọjọ kẹfa, osu Kẹta ninu ọdun 2055.

Alaga ajo Inec naa, fikun ọrọ rẹ wipe awọn orilẹede lagbaye to ti yege ninu eto oselu tiwantiwa, ma n se ikede ọjọ idibo ni ọgọọrọ ọdun sehin ko to di wipe, ọdun naa yoo de.

Yakubu salaye wipe idi ti awọn fi n se ipolongo yii sile ni lati jẹki awọn tọrọ naa kan se igbaradi to peye lakoko ati lati lati mu idagbasoke ba eto oselu lorilẹede Naijria.