Saraki: ọpọ ileeṣẹ ijọba ni ko nii lẹtọ si eto iṣuna 2018

Aarẹ ile asofin agba orilẹede Naijiria, Bukọla Saraki Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Osu kẹrin lẹyin ti Aarẹ Buhari gbe aba eto isuna ọdun 2018 kalẹ, ko tii lojuutu niwaju awọn asofin apapọ

Ile igbimọ asofin agba lorilẹede Naijiria ti fun awọn ileesẹ ati lajọlajọ ijọba apapọ gbogbo di ipari ọsẹ to nbọ lati fi farahan niwaju igbimọ tẹẹkoto gbogbo to yẹ lati fi jiroro lori aba isuna ọdun 2018.

Ile asofin agba naa ni eyikeyi ileesẹ ijọba tabi lajọlajọ ti ko ba farahan yoo padanu ipin rẹ ninu eto isuna ọdun 2018.

Awọn asofin agba orilẹede Naijiria koro oju si bii awọn lajọlajọ ati ileesẹ ijọba apapọ se n mu ki ayẹwo ati igbọwọle abadofin isuna orilẹede Naijiria fun ọdun 2018 o falẹ nipa iha kokanmi ti wọn n kọ sii.

Nigba to n sọrọ, aarẹ ile asofin agba orilẹede Naijiria, Bukọla Saraki ni o seni laanu wi pelẹyin o rẹyin bi awọn ọmọ orilẹede Naijiria ba fẹ di ẹbi fifalẹ eto isuna ru ẹnikẹni awọn asofin ni wọn maa n dii le, ti o si jẹ wi pe ẹka isejọba gan an ni igi wọrọkọ tii da ina igbọwọle eto isuna ru.

Sẹnatọ Saraki ni afojusun awọn asofin apapọ ni lati rii wipe apapọ eto isuna orilẹede Naijiria ati ti awọn ileesẹ ijọba apapọ gbogbo pari lasiko kan naa.

"Ifẹnuko wa ni wi pe ki a fun awọn ileesẹ ati lajọlajọ ijọba apapọ wọnyii ni anfani di opin ọsẹ ti o m bọ. Eyikeyi ti ko ba ti wọle ni opin ọsẹ ti o m bọ, n se ni ki awọn igbimọ to wa ni ikawọn wọn o maa ba isẹ lọ pẹlu awọn ti o ba wa larọwọto."

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí