Aarẹ ọna kakanfo Yoruba marun to jẹ kẹyin

Alaafin Ọyọ, Adeyẹmi III n gbe ọpa asẹ fun Aarẹ Gani Adams

Oríṣun àwòrán, facebook/Aare Gani Abiodun Adams

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Gani Adams ni Aana kakanfo karundinlogun

Oju eeyan pataki ni Yoruba fii wo awọn ologun laye atijọ. Nitori Yoruba gbagbọ wi pe awọn akin nii lọ s'ogun, ẹmii wọn ni wọn si n fi si ori aala lati daabobo ilu.Aarẹ ọna kakanfo ni olori awọn ologun ilẹ Yoruba nigba iwasẹ.

"Aarẹ" tumọ si olori patapata to ba lori ohun gbogbo. "Ọna" ni ojuna ti eeyan n gba tabi tọ. "Kakanfo" tumọ sii 'ka-ka-ka-nii-fo'

Awọn ọrọ wọnyii ni awọn onimọ nipa itan ni a so pọ lati mu orukọ oye nla yii, "Aarẹ ọna kakanfo" Asiko alaafin Ajagbo si ni itan sọ wipe a ti kọkọ loo.

Eyi ni awọn Aarẹ ọna kakanfo marun to jẹ kẹyin:

Àkọlé àwòrán,

O le ni irinwo ọdun sẹyin ti aarẹ kakanfo akọkọ jẹ nilẹ Yoruba

Ojo Aburumaku

Ojo Aburumaku ni Aarẹ Ọna kakanfo kọkanla. Ọmọ bibi ilu Ogbomọsọ ni. Itan sọ wipe yatọ si wi pe o jẹ aarẹ, Ojo Aburumaku tun pada wa jẹ Sọun ti ilu Ogbomọsọ. Sọun ni orukọ ti wọn n pe ọba ilu Ogbomọsọ.

Ko si ogun lasiko rẹ ṣugbọn itan sọ wi pe, lọna ati lee ri ogun ja, ki o si jẹwọ orukọ rẹ gẹgẹbii aarẹ, Ojo Aburumaku da wahala iditẹ gbajọba kan silẹ ni aarin ilu oun tikalara rẹ. Oun funrarẹ lo tun pada wa pa ina ọtẹ yii.

Àkọlé àwòrán,

Alaafin Ọyọ nikan lo lee fi aarẹ Kakanfo

Iyanda Ọbadoke Aubiaro Latooa

Ni ọjọ kẹta oṣu kẹwa ọdun 1871 ni wọn fi Iyanda Aṣubiaro Latoosa jẹ aarẹ ọna kakanfo. Aarẹ Latooṣa ni aarẹ kejila to jẹ. Oun si ni ọmọ ilu Ibadan keji ti yoo jẹ oye alagbara yii lẹyin Oluyedun. Ilu Ilọra ni itan sọ wipe Latoosa ti wa si ilu Ibadan nibi ti o ti darapọ mọ ikọ ọmọogun Ogunmọla, akọni jagunjagun ni ilu Ibadan.

Àkọlé àwòrán,

Aláàfin Àjàgbó lo kọkọ fi aarẹ ọna kakanfo jẹ

Oniruru ogun ni wọn ja lasiko Latoosa sugbọn eyi to gbajugbaja ni bẹ ju ni ogun kiriji ti wọn ja fun ọdun mẹrin.

Lọdun 1885 ni Aarẹ Latoosa jade laye.

Ladoke Akintọla

Ladoke Akintọla ni Aarẹ ọna kakanfo kẹtala to jẹ.

Oloṣelu haunhaun ni Akintọla, ọmọ ilu Ogbomọsọ si ni.

Oríṣun àwòrán, Olarewaju Onigegewura

Àkọlé àwòrán,

Meji ninu awọn aarẹ ọna kakanfo marun to jẹ kẹyin ni wọ̀n jẹ oloselu

Ni osu kẹjọ ọdun 1964 ni wọn fi Ladoke Akintọla jẹ gẹgẹbii aarẹ ọna kakanfo.

Akintọla ni igbakeji gbajugbaja oloṣelu ni, Oloye Awolọwọ lẹgbẹ oṣelu Action Group.

Oun yii kan naa ni igbakeji oloye Awolọwọ ni iṣejọba ẹkun iwọ oorun ilẹ Naijiria nigbanaa.

Àkọlé àwòrán,

Awọn jagunjagun to to gbangba sun lọyẹ nii jẹ aarẹ

Amọsa, ija bẹẹlẹ laarin awọn agba oselu mejeeji yii to si mu ki Akintọla o di ero ẹgbẹ oselu NNDP

Lasiko iditẹgbajọba awọn ologun to kọkọ waye lorilẹede Naijiria lọdun 1966 ni wọn ti pa Akintọla. Nigba naa ọhun ni olotu ijọba ẹkun iwọ oorun orilẹede Naijiria.

Moshood Kaṣimawo Olawale Abiọla

Moshood Kasimawo Olawale Abiọla ti gbogbo eeyan mọ si MKO ni Aarẹ ọna kakanfo kẹrinla to jẹ. Oniṣowo to gbajugbaja kaakiri agbaye ni MKO Abiọla jẹ. Ọmọ bibi ilu Abẹokuta si ni. Itan igbesi aye rẹ fi ye wa wi pe, atapata dide ni MKO Abiọla sugbọn nipa ifọkansin ati itẹpamọsẹ, o di eeyan pataki.

Oríṣun àwòrán, olanrewaju Onigegewura

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Kakanfo kii saba n ba alaafin gbe ilu

Yatọ si wipe o jẹ onisowo, ohun kan ti o tun mu ki araye fẹ Abiọla ni bi o se fẹran lati maa fi owo ṣaanu fun awọn ti ko ni.

Ni ọjọ kẹrinla, oṣu kini ọdun 1988 ni wọn fi Abiọla jẹ oye aarẹ ọna kakanfo.

Lọdun 1998 ni MKO Abiọla papoda ni ahamọ ijọba ologun lẹyin to ja fitafita lati gba ipo rẹ gẹgẹbi ẹni ti ilu dibo yan sipo aarẹ orilẹede Naijiria lọdun 1993.

Oríṣun àwòrán, Olarewaju Onigegewura

Àkọlé àwòrán,

Ayipada diẹ ti de ba oye aarẹ ọna kakanfo nitori ko si ogun mọ ni ilẹ Yoruba

Gani Adams

Ọmọ ilu Arigidi-Akoko ni ipinlẹ Ondo lẹkun iwọoorun gusu orilẹede Naijiria ni Gani Adams.

Ohun ni Aarẹ ọna kakanfo karundinlogun to jẹ.

Oríṣun àwòrán, @ganiadams01

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Marundinlogun lo ti jẹ ninu itan Yoruba

Ni oṣu kini ọdun 2018 ni Gani Adams bọ si ipo aarẹ Ọna kakanfo.

Ṣaaju iyansipo rẹ, Gani Adams ni olori ẹgbẹ ọmọ Yoruba ti wọn n pe ni Oodua Peoples Congress, OPC.