Ọmọ Aarẹ Buhari pada de lẹyin itọju nilẹ okeere

Aare Buhari nki Yusuf kaabọ

Oríṣun àwòrán, @aishambuhari

Àkọlé àwòrán,

Yusuf ko gba itọju ni Naijiria ki wọn to gbe lo ile okere

Ọmọ Aarẹ orilẹẹde Naijiria, Yusuf Buhari, ti pada de lati ilẹ okeere nibi ti o ti'n gba itọju.

Yusuf Buhari f'ara pa ninu ijamba alupupu lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kejila ọdun to kọja.

O kọkọ gba itọju ni ile iwosan Cedar Crest ko to di wi pe wọn gbe e lọ si ilẹ okeere fun itọju.

Oríṣun àwòrán, @aishambuhari

Àkọlé àwòrán,

Aisha Buhari dupẹ lọwọ ọmọ Naijiria fun aduroti wọn

Mama rẹ Aisha Buhari kede ipadade rẹ lori oju opo twita re.

''A dupẹ fun ipadabọ ọmọ wa Yusuf loni lẹyin itọju nilẹ okeere, Minista fun eto ilera lo pade rẹ ni papakọ ofurufu''

Ikede na ko darukọ ibi ti Yusuf ti lọ gba itọju.

Lai pẹ yi ni iroyin tan kaakiri pe Yusuf ti ku ṣugbọn ijọba ni ko si ootọ ninu iroyin naa.

Lẹyin igba naa ni awọn eniyan tun ni wọn ti gbe e lọ si Germany fun itọju.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: