Wọn ra iṣẹ ona Tutu ni miliọnu pọun kan ni London

Aworan isẹ ona Adetutu Ademiluyi Image copyright Bonhams
Àkọlé àwòrán O le ni ogoji ọdun ti wọn fi wa ise ona ''Tutu'' ti Ben Enwonu ya.

Iṣẹ ọna ilẹ Naijiria kan to ṣadede suyọ ni filati onile kẹjẹbu kan ni ariwa ilu London ti pa owo to le ni miliọnu pọun kan lọja gbanjo.

Isẹ ọna naa, to jẹ aworan Ọmọọba Adetutu Ademiluyi ti Ilẹ Ife, eyi ti Ben Enwonwu ya ni ọdun 1974 di ami iṣọkan orilẹẹde Naijiria lẹyin ogun abẹle Biafra.

Wọn lero wi pe iṣẹ ọna naa yoo mu ẹgbẹrun lọna ọọdunrun pọun wa ṣugbọn wọn ti san miliọnu kan le diẹ fun un nigba ti wọn lu u ni gbanjo.

Eyi jẹ owo to pọ ju ti iṣẹ ọna igbalode lati ọwọ omo orilẹẹde yi yoo pa.

Ben Okri, to je akọwe ami ẹyẹ Booker ni ''iṣẹ ọna yi jẹ ọkan gbogi ti wọn ṣe awari rẹ ni bii aadọta ọdun sẹyin''

Image copyright Bonhams
Àkọlé àwòrán Ọpo eeyan ri Ben Enwonwu gẹgẹ bi oludasile ise ọna igbalode lorilẹẹde Naijiria

Alakoso iṣẹ ọna igbalode ni ile afihan iṣẹ ọna Bonham, Giles Peppiatt ni ẹni to ri iṣẹ ọna Adetutu nigbati ẹnikan ni ko wa a ṣe ayẹwo rẹ ni filati onile kẹjẹbu kan ni ariwa ilu London.

Peppiat ni loorekore ni awọn eeyan maa n ni ki ohun wa wo irufẹ iṣẹ ọna naa ti o si jẹ wi pe ọpọ ninu wọn ni kii ṣe ojulowo.

Ko si ẹni to mọ bi iṣẹ ọna naa ti ṣe kangun si filati naa ṣugbọn awọn to ni iṣẹ naa ni ki wọn f'orukọ bo awọn laṣiri.

Ọgbẹni Enwonwu, ti ọpọ eeyan ri gẹgẹ bi oludasilẹ iṣẹ ọna igbalode lorilẹede Naijiria ya oriṣi mẹta ẹẹda aworan Tutu.

Awọn aworan mẹta ọhun di awati lẹyin iku rẹ lọdun 1994.

Ko si ẹni to mọ ibi ti awọn aworan meji toku wa.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: