Emeka Monye: Gbogbo ibi kọ ni ọga ọlọpaa gbọdọ lọ kato ni aabo to peye

Aworan ọga ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police

Àkọlé àwòrán,

Danbazzau paṣẹ fun ọga ọlọpaa ati ọga ajọ abo ara ẹni labo ilu pe ki wọn kọri si ẹkun ila oorun ariwa

Eyi ni aṣẹ ẹlẹkeji ti ọga ọlọpa yoo gba lẹnu igba ti ipenija ọrọ aabo ẹmi bẹrẹ si ni suu yọ lawọn apa kan orilẹẹde yi.

O ni ki wọn lọ ṣẹto aabo f'awọn ileewe to wa lẹkun naa ni ifọwọsowọpọ awọn ọmọ ogun to wa nilẹ.

Onimọ nipa ọrọ aabo, Emeka Monye ni aṣẹ yi dara ṣugbọn ọna melo ni ọga ọlọpaa fẹ pin ara rẹ si?

O beere wi pe ''ṣe gbogbo ibi ti wahala ba wa ni ọga ọlọpaa yoo maa ko lọ ni?

''Ki lo ṣẹlẹ si gbogbo owo ti a na lori ọrọ eto aabo? Abi wọn ko ṣiṣẹ mọ ni?''

Àkọlé fídíò,

Ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Emeka Monye

Ẹwẹ, o ni ohun to ṣe pataki ni ki gbogbo awọn oṣiṣẹ eto aabo jọ pawọpọ lati dẹkun ipenija aabo ẹmi to ba orilẹede Naijiria.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: