Ọpa epo muna ni ijegun, nipinlẹ Eko

Ọpa epo muna ni ijegun, nipinlẹ Eko Image copyright Ohi Odiai
Àkọlé àwòrán Iṣẹlẹ ibugbamu ọpa epo ni odun 2015 mu ọpọ ẹmi lọ

Iroyin ti tẹ ileeṣẹ BBC Yoruba lọwọ wipe awọn ọpa epo betiroolu kan ti gbana ni agbegbe Ijegun ni Ipinlẹ Eko.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ panapana ti ipinlẹ Eko, Amodu Sakiru ti o f'idi iṣẹlẹ yi mulẹ sọ wipe awọn ti n gbiyanju lati dẹkun jamba yi ati wipe ko la ẹmi kan kan lọ.

Image copyright Ohi Odiai
Àkọlé àwòrán Awon panapana gbiyanju lati dẹkun ijamba yi

Alukoro ileeṣẹ ti o n risi iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko (LASEMA) sọ fun BBC pe iṣẹlẹ naa waye nitori pe awọn afurasi ọdaran kan fẹ wa epo rbi jade ninu ọpa epo naa ki ina too bu yọ nibẹ.

O ṣalaye siwaju sii wipe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa ti wa nibẹ pẹlu awọn agbofinro, pẹlu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si:

Related Topics