Awọn oluwọde ya wọ ile-ẹjọ nitori aṣofin Dino Melaye

Image copyright Dino Melaye/Facebook
Àkọlé àwòrán Wọ́n gbé Dínò Mèláye lọ́ ilé ẹjọ nitori ẹ̀sun ìkuro lorí ìgbìyànju láti paa

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti gbe aṣofin Dino Melaye lọ s'ile-ẹjọ giga ti ilu Abuja lori awọn ẹsun meji to niiṣe pẹlu ijẹri-eke ati irọ pipa wipe awọn eniyan kan fẹ d'ẹmi rẹ legbodo ni oṣu kẹrin ọdun ti o kọja.

Melaye n j'ẹjọ niwaju adajọ Olasumbo Goodluck nitori pe o purọ mọ olori oṣiṣẹ ni ọfiisi Gomina ipinlẹ Kogi, ọgbẹni Edward Onoja pẹlu ẹsun ipaniyan.

Dino Melaye lọ si ile-ẹjọ pẹlu ogunlọgọ awọn eniyan ti wọn n kin lẹyin.

Awọn aṣofin ati awọn oluwọde yi ya wọ ile-ẹjọ naa l'Abuja ti wọn si i fẹhonuhan lori bi ijọba ṣe gbe aṣofin Dino Melaye lọ sile ẹjọ.

Awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ti wọn tẹle Dino lọ gbẹjọ ni awọn bii Philip Aduda, Shehu Sani, Tayo Alasoadura, Ben-Murray Bruce ati awọn miiran.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: