Ile asofin: A nfẹ adinku agbara ijọba apapọ

Ile igbimọ aṣọfin agba Image copyright @NigerianSenate
Àkọlé àwòrán Ile igbimọ aṣọfin apapọ tako igbesẹ gbigbe agbara wọ awọn ipinlẹ

Igbimọ awọn ile asofin ipinlẹ ti tako ile igbimọ aṣofin apapọ lori bo se lodi si gbigbe agbara wọ awọn ijọba pinlẹ lati ọwọ ijọba apapọ.

Alaga igbimọ ile-aṣofin ipinlẹ, Abdulmumin Kamba, lo sọ eleyi di mimọ ko to gbe awọn atunṣe iwe ofin ajọ naa le aarẹ ile igbimọ aṣofin apapọ, Bukọla Saraki, lọwọ.

Ọgbẹni Kamba bu ẹnu atẹ lu ipinnu ile igbimọ aṣofin apapọ lori ọrọ naa.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Kamba to jẹ olori ile-igbimọ aṣọfin ipinlẹ Kebbi bẹ awọn aṣọfin apapọ wipe ki wọn yi ipinnu wọn pada lori ọrọ naa.

Lọdun 2017 lọgọọrọ awọn aṣọfin apapọ Naijiria tako igbesẹ gbiigbe agbara wọ awọn ipinlẹ si .