Ile igbimọ asofin ‘dibo mi o nigbagbọ ninu rẹ’ si Kayọde Fayẹmi

Ọmọwe Fayẹmi ni ere ọmọde ni igbesẹ ijọba fayose lati fofin de oun

Oríṣun àwòrán, Fayemi /twitter

Àkọlé àwòrán,

Ijọba ipinlẹ Ekiti f'ofin de Fayemi fun ọdun mẹwa losu to koja

Ile-Igbimọ Asofin ti ‘dibo mi o ni igbagbọ ninu rẹ’ si Minisita fun nkan alumọni lorilẹede Naijiria, Kayọde Fayẹmi ati igbakeji rẹ, ọgbẹni Abubakar Bawa-Bwari.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni wipe, awọn mejeeji kuna lati yọju sibi ifọrọwerọ ti ile aṣofin pe wọn si, lori ọrọ alumọni orilẹede yii ati ọna abayọ sibi idẹnukọle Ajaokuta Steel Plant.

Adari Ile-Igbimọ Asofin, Ọgbẹni Fẹmi Gbajabiamila lo ṣaaju igbesẹ lati dibo ‘mi o ni gbagbọ ninu rẹ’.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: