Fayẹmi fesi si 'ibo mi o nigbagbọ ninu rẹ'

Ijọba ipinlẹ Ekiti f'ofin de Fayemi fun ọdun mẹwa losu to koja

Oríṣun àwòrán, @kfayemi

Àkọlé àwòrán,

Ijọba ipinlẹ Ekiti f'ofin de Fayemi fun ọdun mẹwa losu to koja

Minisita fun nkan alumọni, Kayọde Fayemi, ti sọ wipe igbimọ aṣojuṣofin Naijiria roro pọ lori ibo 'mi o nigbagbọ ninu rẹ' tigbimọ naa di fun.

Ile-igbimọ aṣofin dibo yii lori Kayọde Fayemi ati minisita kekere fun nkan alumọni, Abubakar Bawa-Bwari, nitori wipe wọn kuna lati lọ ibi ifọrọwerọ lori ipo ti ẹka irin ọrọ-aje Naijiria wa.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ministia naa, Ọlayinka Oyebọde, fi sita, o sọ wipe awọn minisita mejeji ti ṣalaye idi ti wọn ko fi lọ sibi ifọrọwerọ naa.

O ni aidọgba ni sisọ wipe awọn minisita naa mọmọn ma lọ sibi ti wọn pe wọn si.

Agbẹnusọ fun minisita naa sọ wipe o ye ki awọn aṣofin naa tunbọ ni ifarada ati ṣiṣe nkan niwọntunwọnsi.

Adari Ile-Igbimọ Asofin, Ọgbẹni Fẹmi Gbajabiamila lo ṣaaju igbesẹ lati dibo 'mi o ni gbagbọ ninu rẹ' naa.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: