Ipinlẹ Eko wọ 70 afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun lọsile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government
Nibi ti wọn ti'n se ipade lago meji oru ni ọlọpaa ti ko wọn
Ijọba ipinlẹ Eko ti wọ awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun aadọrin lọ si waju ile ẹjọ kekere.
Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni iwaju adajọ Olufunke Sule Amzat ni lilẹdi apo pọ lati huwa ọdaran ati kikojọ labẹ asia ẹgbẹ to lodi s'ofin eleyi ti wọn fura si pe o jẹ ẹgbẹ okunkun aiye.
Ẹka to'n dari fifẹsun kan ni labẹ ile iṣẹ eto idajọ lo fi ẹsun mẹta kan awọn afurasi naa ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mọkandinlogun ati ogoji ọdun.
Oríṣun àwòrán, Lagos State Government
Wọn nṣe ipade ni agogo meji oru ladugbo Ẹlemoro ni Ajah
Ṣaaju ni awọn agbofinro mu wọn lọjọ kẹtalelogun oṣu keji lẹyin ti awọn araadugbo tawọn lolobo pe awọn afurasi naa n ṣe ipade ni nnkan bi agogo meji oru ladugbo Ẹlemoro ni Ajah.