Ọwọ ọlọpa tẹ alufa, eeyan mẹrin miran fun jijọmọgbe l'Ọsun

Alufa ati awọn afunrasi merin duro ti ara wọn

Oríṣun àwòrán, R. Rasheed

Àkọlé àwòrán,

Ajọsepọ ọlọpa ipinlẹ Osogbo ati Anambra lo sokunfa awari ọmọde jojolo naa

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpa ti tẹ alufa kan atawọn eeyan mẹrin miran fun lilọwọ ninu ẹsun jiji ọmọgbe ni ipinlẹ Osun.

Ikọ ajọmọgbe yii lawọn ọlọpa ni wọn ji ọmọde jojolo kan ti orukọ rẹ n jẹ, Abdullahi Afeez gbe ni ilu oṣogbo ti wọn si lẹ taa fun arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Maxwell ni ipinlẹ Imo fun owo to to ẹgbẹrun lọna irinwo naira.

Awọn meji ninu awọn afunrasi ọdaran yii ti wọn jẹ tọkọ tiyawo pẹlu tun jẹwọ fun awọn ọlọpa wipe awọn gan an funra awọn ti ta ọmọ awọn meji fun ọgbẹni Maxwell yii kan naa ti o ni ile itọju ọmọ alainiya kan nipinlẹ Osun.

Oríṣun àwòrán, facebook/Fimihan Adeoye

Àkọlé àwòrán,

Ọlọpa yoo sewadi boya awọn miran si lọwọ ninu oowo kotọ yii

Amọṣa, akara tu s'epo fun awọn afunrasi naa nigbati Maxwell ta Abdullahi Afeez fun arabinrin kan ti orukọ rẹ njẹ Elizabeth fun ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin o din aadọta naira ti o si tun n beere aadọta ẹgbẹrun miran lati fi ṣe iwe isọdọmọ ti ijọba laimọ wipe jiji n lo ji ọmọkun naa gbe.

Arabinrin Elizabeth ni alufa Ugwuejiofor Chicke to jẹ alufaa ijọ rẹ lo juwe Maxwell fun oun ti o si gba awọn owo naa pẹlu.

Bi o tilẹ jẹ wi pe alufa Ugwuejiofor Chicke ni oun ko mọ Maxwell ri, atipe oun kan fi oju aje konisọ laarin Maxwell ati Elizabeth ni niwọn bi oun se mọ Maxwell gẹgẹbi eeyan to gba iwe asẹ lati ni ile ọmọ alainiya.

Bakanna lawọn ọlọpa sọ wipe arabinrin Elizabeth ti yi orukọ ọmọ naa pada si Chukwuemeka.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: