Dogara: Aṣofin ipinlẹ ja awọn ọmọ Naijiria kulẹ lori ominira ijọba ibilẹ

Olori ileegbimọ asofin apapọ mejeeji, Asofin Dogara ati Saraki n tẹwọ gba iwe afẹnuko awọn ileegbimọ asofin ipinlẹ Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Asofin Dogara ni igbesẹ ati fagile abala ominira fawọn ijọba ibilẹ dun oun d'ọkan

Olori ileegbimọ aṣojuṣofin lorilẹede Naijiria, Aṣofin Yakubu Dogara ti fi aidunu rẹ han lori bi awọn ileegbimọ aṣofin ipinlẹ ti ṣe kuna lati bu'wọlu abala fifun awọn ijọba ibilẹ ni ominira labẹ eto atunṣe iwe ofin orilẹede Naijiria to n lọ lọwọ.

Aṣofin Yakubu Dogara sọrọ yii lẹyin ti awọn ileegbimọ aṣofin ipinlẹ ti gbe abajade ibo ti wọn di lori awọn abala kọọkan ti wọn fẹ tun ṣe ninu iwe ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999 pada wa fun awọn aṣofin apapọ nilu Abuja lọjọọbọ.

Image copyright @YakubDogara
Àkọlé àwòrán Dogara ni igbesẹ awọn asofin ipinlẹ se afihan ọkan akin awọn asofin lorilẹede Naijiria

Aṣofin Dogara ni lootọ ni igbesẹ ati ifagile abala ominira fawọn ijọba ibilẹ dun oun d'ọkan sibẹ oun ko ni ṣai kan saara si iwa akin ti awọn ileegbimọ aṣofin ipinlẹ hu lori ọrọ naa.

"Lootọ ọrọ yii kii ṣe ọrọ ileegbimọ aṣofin apapọ o ṣugbọn iha ti emi gẹgẹ bii ẹnikan kọ sii.

"Ireti mii ni wipe awọn akinkanju aṣofin wọnyii yoo gbe igbesẹ lati fun awọn ijọba ibilẹ ni ominira to tọ si wọn."

Amọṣa o ni eyi kọ ni opin igbesẹ lori ominira awọn ijọba ibilẹ nitori gẹgẹbi o ṣe sọ awọn aṣofin ipinlẹ lee yi ọkan wọn pada nigba ti ileegbimọ aṣofin apapọ ba tun gbee tọ wọn wa lẹẹkan sii.

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Atunṣe iwe ofin ọdun 1999 ti bẹrẹ lorilẹede Naijiria

Olori ileegimọ aṣofinṣoju ni bi o tilẹ jẹ wi pe awọn ilana tuntun ti awọn aṣofin apapọ n gbe bayii lee maa ba ọpọ lara mu, ṣugbọn bi wọn ba duro ṣinṣin lorii wọn yoo so eso rere fun idagbasoke eto iṣejọba tiwantiwa lọjọ iwaju.

"Gẹgẹbi abala ipese ominra iṣuna f'awọn ileegbimọ aṣofin ipinlẹ ṣe kuna nigbakanri, o ṣeeṣe ki ọsan o so didun fun igbesẹ yii nigba miran.

"Nitori bayii, ominira ti de ba awọn ileegbimọ aṣofin wa, awọn naa yoo lee na ọwọ ominira yii si awọn ijọba ibilẹ bopẹ-boya."

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Oniruru awuyewuye lo ti n wọ tọ igbesẹ ominira fun ẹka ijọba ibilẹ lorilẹede Naijiria

Bakannaa ni Aṣofin Dogara tun ke si Aarẹ Muhammadu Buhari lati bu'wọlu abadofin naa lẹyẹ o sọka niwọn igba to jẹ wi pe ifẹ ọkan awọ ọmọ orilẹede Naijiria gan an lo gbe kalẹ lati ọdọ awọn ileegbimọ aṣofin apapọ ati ti ipinlẹ.

Lara awọn abala ti awọn aṣofin ipinlẹ lorilẹede Naijiria bu'wọlu ninu atunṣe tuntun naa ni didi akoko fun akanṣe afikun eto iṣuna latọdọ ẹka iṣejọba lati oṣu mẹfa si mẹta, ofin koṣee bawijọ fawọn aṣofin, ofin tuntun fun ṣiṣeto atundi ibo ati atunṣe orukọ ileeṣẹ ọlọpa, fifi saa aarẹ ati awọn gomina si ọdun mẹjọ, mimu adiku ba ọjọ ori fun didi ipo oṣelu mu, fifi gbedeke lelẹ fun agbekalẹ eto iṣuna latọdọ aarẹ ati fifi ọrọ ileeṣẹ abo ara ẹni laabo ilu sinu iwe ofin orilẹede Naijiria.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: