Ominira ijọba ibilẹ: Iṣẹ awọn gomina l'awọn aṣofin jẹ, kii ṣe iṣẹ araalu

Igbakeji olori ileegbimọ asofin ipinlẹ Ọsun, Niyi Owolade Image copyright Niyi Owolade/Facebook
Àkọlé àwòrán Awọn asofin ipinlẹ bẹru gomina ju araalu to yan wọn sipo lọ

Amofin kan to ti figbakan ri jẹ igbakeji olori ileegbimọ asofin ipinlẹ Ọsun, Niyi Owolade ti sọ wipe ohun ti awọn asofin ipinlẹ gbe kalẹ fun awọn asofin apapọ lori atunse awọn abala kan ninu iwe ofin orilẹede Naijiria kiise ohun araalu bikose ohun awọn gomina ipinlẹ gbogbo lorilẹede yii.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, amofin Owolade ni ko si aniani wi pe ọpọ awọn ileegbimọ asofin lo ti di amuṣere fun awọn gomina wọn ti o si jẹ wi pe ohun ti awọn gomina wọn ba n fẹ ni wọn nṣe dipo ohun ti araalu ran wọn.

"O ti pẹ ti awọn gomina ipinlẹ o ti fẹ ominira fun awọn ijọba ipinlẹ wọn. Awọn asofin ko se ohun to yẹ ki wọn ṣe. Awọn gomina lo n la le awọn asofin lọwọ. Awọn gomina ni ko fẹ ki ominira fun ijọba ibilẹ. Nkan ti wọn si fọn si inu fere fun awọn asofin ipinlẹ ni wọn fọn fun araalu."

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán 'Atunto orilẹede Naijiria ni yoo pẹtu si gbogbo ohun ti awọn asofin apapọ ati ti ipinlẹ n sisẹ lori bayii'

Amofin Owolade to tun jẹ ọkan pataki ọmọ ẹgbẹ Afẹnifẹre ni ibẹrubojo ni ọpọlọpọ awọn asofin ipinlẹ fi n sofin nitori wọn bẹru awọn gomina ipinlẹ ju araalu gan an to fi wọn sipo.

O wa ke si awọn asofin to wa nipo bayii lorilẹede Naijiria lati mojuto ifidimulẹ atunto oriulẹede Naijiria, eyi to ni o mumu lọkan awọn ọmọ orilẹede naa ju gbogbo ohun ti wọn gbe lọwọ bayii.

Amofin Owolade ni atunto orilẹede Naijiria ni yoo pẹtu si gbogbo ohun ti awọn asofin apapọ ati ti ipinlẹ n sisẹ lori bayii.

"Nitori atunto ilana isakoso orilẹede Naijiria ti a n pariwo rẹ sugbọn ti ijọba o fẹ sugbọn ti araalu n fẹ ni ki awa ọmọ orilẹede yii o joko, nitoripe gbogbo ija to wa lorilẹede yii bayii tori atunto yii ni."

Ni ọjọbọ ni awọn aṣofin ipinlẹ gbe abajade apero wọn lori atunṣe awọn abala kan ninu iwe ofin Naijiria le awọn aṣofin apapọ lọwọ ninu eyi ti wọn ti kọ ipakọ si abala ominira fun awọn ijọba ibilẹ.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: