Bukola Saraki: Ko s'ohun to pamọ lori aisi nibi ipade APC mi

Alaga ẹgbẹ oselu APC Oloye Oyegun duro o kọju si Aarẹ Buhari to joko pẹlu igbakeji rẹ, Ọjọgbọn Osibajo ati Gomina Okorocha ti ipinlẹ Imo Image copyright @AsoRock
Àkọlé àwòrán Ẹnu n kun ẹgbẹ oselu APC lorilẹede Naijiria lori oniruuru awuyewuye abẹnu to n waye nibẹ

Ni ọjọ aje ni ẹgbẹ oṣelu APC ṣe awọn ipade meji ti o ṣe koko fun ilọsiwaju ẹgbẹ oselu naa paapaajulọ ni imurasilẹ fun eto idibo apapọ ọdun 2019.

Akọkọ ni ipade igbimọ agba ẹgbẹ naa ati igbimọ isakoso ẹgbẹ oselu ọhun.

Bi awọn ipade wọnyii ṣe ṣe pataki to, aarẹ ile asofin agba lorilẹede Naijiria, Sẹnatọ Bukọla Saraki ko si ni ibi ipade mejeeji.

Oniruuru ọrọ si ni awọn eniyan ti n sọ, paapaajulọ pẹlu bi awuyewuye ati dukuu abẹnu se n fara han lẹgbẹ oselu naa.

Saraki ti wa salaye wi pe aisi nile oun lọjọ aje lo faa ti oun ko fi kopa nibi ipade igbimọ agba ẹgbẹ oselu APC.

Ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ lori ọrọ iroyin fun Saraki, Yusuf Ọlaniyọnu, se sọ ko si ohunkohun to lee ba Saraki laya lati ma se farahan ninu ipade yoowu nibikibi.

Image copyright @AsoRock
Àkọlé àwòrán Abajade ipade igbimọ isakoso APC tun mu akọtun awuyewuye jade pẹlu afikun saa igbmọ isakoso rẹ labẹ isakoso oloye Oyegun

"Lọjọ aje, saraki wa nibi ijiroro lori didẹkun wahala fifi awọn eeyan sowo kotọ lorilẹede naijiria eleyi ti ile asofin apapọ pe nilu Benini. Ko si si bi Sẹnatọ Saraki se lee wa ni ilu Benini ti yoo tun wa nilu Abuja.

Lọjọ Isẹgun ẹwẹ, lasiko ti ipade igbimọ isakoso ẹgbẹ oselu APC n lọ lọwọ ni aarẹ ile asofin apapọ wa niwaju ileẹjọ lori ẹsun pe ko sootọ lori kikede dukia rẹ ki o to de ipo. Saraki si kọ lo mu ọjọ fun igbọjọ yii. Aja kii roro ko sọ ojule meji. Ko si bi saraki se lee wa ni ile ẹjọ yii ko tun wa pẹlu ipade ẹgbẹ oselu APC."

O ni ko si idi kan lẹyin bi Saraki ko se si nibi ipade ẹgbẹ oselu APC atipe awọn agbọyisọyi ẹda kan lo wa nidi awuyewuye yii.

O ni ko tii si ohun kan to yatọ ninu idurosinsin Saraki ninu ẹgbẹ oselu APC nitori asiwaju ati ọkan ninu awọn oludasilẹ ẹgbẹ oselu naa ni.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: