Ijinigbe Dapchi: Awọn olori ileesẹ aabo tẹdo si Dapchi

Ọgagun ileesẹ ọmọogun ofurufu, Sadique Abubakar pẹlu alakoso eto aabo patapata lorilẹede Naijiria, Ajagunfẹyinti Babagana Monguno n ki ara wọn Image copyright @NigAirForce
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari ti seleri wi pe gbogbo ọna nijọba yoo gba lati sawari awọn akẹkọ Dapchi

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti ko gbogbo awọn olori ileesẹ ologun lorilẹede Naijiria lọ si ẹkun ila oorun ariwa orilẹede yii lati tẹsiwaju nidi wiwa awọn ọmọ ileewe girama ilu Dapchi nipinlẹ Yobe tawọn agbebọn Boko haram ji gbe.

Ọgagun agba patapata lorilẹede Naijiria, Ọgagunagba Abayọmi Olonisakin, olori ileesẹ ọmọogun oju omi, Ibok-Ete Ekwe Ibas, Ọgagun ileesẹ ọmọogun orilẹ, Tukur Buratai ati oludari agba fun ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ ni Naijiria, (SSS) Alhaji Lawal Daura ni ijọba apapọ ti pasẹ fun pe ki wọn kọri si ẹkun naa.

Image copyright @NigAirForce
Àkọlé àwòrán Ijọba apapọ apapọ ti kede saaju wipe afikun ti de ba awọn ọmọogun to wa nilẹ lati wa awọn akẹkọ to sọnu

Atẹjade kan ti minisita feto iroyin lorilẹede Naijiria, AlahajiLai Muhammed fisita ni, asẹ yii ko se lẹyin ipinnu ijọba lati fẹ eto awari awọn akẹkọ naa loju kọja ipinlẹ Yobe bọ si awọn ipinlẹ gbogbo to yii ka.

Awọn asiwaju ikọ alaabo gbogbo lorilẹede Naijiria naa yoo maa darapọ mọ ọgagun ileesẹ ọmọogun ofurufu, Sadique Abubakar pẹlu alakoso eto aabo patapata lorilẹede Naijiria, Ajagunfẹyinti Babagana Monguno to ti digba-dagbọn rẹ lọ ẹkun naa saaju akoko yii.

Saaju ni ijọba apapọ ti fi orukọ aadọfa awọn akẹkọ ti wọn si n wa ni ileewe girama awọn obinrin to wa ni ilu Dapchi ransẹ, ko to di wipe o se ifilọlẹ igbimọ kan lati sọfintoto awọn ohun to rọ mọ bi wọn se ji awọn akẹkọ naa gbe.