Ikọlu Burkina Faso: Wọn yibọn ati ado oloro ni Ouagadougou

Eefin gbalẹ ka ni agbegbe ikọlu yi Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Aṣoju orilẹede France tẹ iwe si oju opo ayelujara twitter rẹ wipe "Ikọlu kan nlọ lọwọlọwọ bayi"

Iro ibọn ati ibugbamu ado oloro gba afẹfẹ ka nigbati awọn agbesunmọmi kọlu olu ileeṣẹ ọmọ ogun ni Ouagadougou.

Awọn ẹlẹri ti n royin pe awọn ri awọn ologun ti wọn n jade kuro ninu ọkọ ayọkẹlẹ kan ti wọn si ṣina ibọn bolẹ.

Awọn aworan lati ibi iṣẹlẹ yi ṣafihan awọsanmọ ti o dudu ni agbegbe naa pẹlu eefin. Ko tii i ẹni ti o mọ awọn ti o ṣokunfa iṣẹlẹ naa bayi.

Aṣoju orilẹede France tẹ iwe si oju opo ayelujara twitter rẹ wipe "Ikọlu kan nlọ lọwọlọwọ bayi".

Awọn ọlọpa ti orilẹ-ede naa ti gbe atẹjade sita wipe awọn ọmọ ogun kogberegbe ti wa lẹnu iṣẹ bayi.

Ile-iṣẹ Amẹrika ti o wa ni ilu naa ti gba awọn eniyan niyanju lati wa ibi aabo.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: