Mama Boko Haram: Alaafia ni akẹẹkọ Dapchi wa

Awọn ọmọ ileewe joko ni gbọngan nla Image copyright Yobe state governmentt
Àkọlé àwòrán O le ni aadọfa akẹkọ Dapchi to tun bọ sọwọ Boko Haram

Gbaju gbaja ajafẹtọ ẹni kan, Aisha Wakili, ti wọn tun ndape ni Mama Boko Haram ti ni awọn akẹẹkọ Dapchi ti ikọ Boko Haram ji gbe laipẹ yi wa ni alaafia pẹlu Habib, ẹni to pe ni ọmọ rẹ.

Wakili fi kun pe kawọn ọmọ Naijiria mase mikan rara nipa ipo tawọn ọmọ Dapchi naa wa nitori eera kankan ko rin won pẹlu ọmọ oun ati awọn ọrẹ rẹ.

O ni igun kan ninu ikọ Boko Haram, Barnawi ti kan si oun lọjọbọ pe ọdọ awọn lawọn ọmọ Dapchi ti wọn ji gbe wa.

Wakil, jẹ ọmọ igbimọ to nrisi eto ifikunlukun ati yiyanju ipenija eto aabo nitunbi nnubi ( Dialogue and peaceful resolution of security challenges committee), ti ijọba Jonathan da silẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ijọba ti da awọn olori ileesẹ́ alaabo atawọn osisẹ wọn sipinlẹ Yobe lati se awari awọn akẹkọ Dapchi

Wakil, ẹni to maa nkan si ikọ Boko haram atawọn asaaju rẹ kede pe oun setan lati fi ẹmi ara oun lelẹ lati doola ẹmi awọn ọmọ Dapchi naa.

"Mo bẹ wọn pupọ, ti mo si ni ki wọn mase jẹ ki awọn akẹkọ yi wa pẹlu wọn fun igba pipẹ, fun ẹgbẹrun ọjọ tabi ju bẹẹ lọ bii tawọn akẹẹkọ Chibok, amọ wọn ko sọ ohunkohun."

"Ọmọ daada ni Habib, ko lee pa wọn lara rara, bẹẹ ni ko ni fi ọwọ kan wọn tabi ko pa wọn"

Wakil fi kun pe oun nrọ awọn ọmọ Naijiria lati se suuru, ki wọn si kun fun adura nitori ohun gbogbo yoo pada yọri si rere.