NUJ ko ni gba kẹ fiya jẹ akọroyin laitọ
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

NUJ: A fẹ mọ ẹsẹ awọn akọroyin tẹ da duro

Aarẹ ẹgbẹ akọroyin ni Naijiria, Waheed Odusile ti gbọnmu lori bi ileesẹ agbohunsafẹfẹ AIT ati ileesẹ itẹwe iroyin The Sun se juwe ọna ile fawọn osisẹ rẹ toto ọọdunrun niye.

Odusile ni ẹgbẹ akọroyin yoo tanna wadi isẹlẹ naa lati mọ ohun tawọn ileesẹ ọhun ri lọbẹ, ti wọn se waaro ọwọ.

O fikun pe ti iwadi naa ba fihan pe wọn kan fẹ fi iya jẹ awọn akọroyin naa lọna aitọ ni, ẹgbẹ NUJ yoo faraya si isẹlẹ yi.

O wa rọ awọn ileesẹ AIT ati The Sun lati san gbogbo ẹtọ awọn akọroyin ti wọn da duro naa, to ba jẹ pe bi wọn se gba isẹ lọwọ wọn ba ofin mu.

Bakan naa ni aarẹ ẹgbẹ akọroyin lorilẹede yi kaanu pe kii se isẹlẹ to dara rara ki awọn eeyan maa padanu isẹ wọn lasiko yi ti ọrọ aje Naijiria ko rẹrin rara.