Ikọlu Boko Haram ti sọ ipinnu wa dọtun — Buhari

Buhari ninu asọoologun Image copyright Twitter/@MBuhari

Aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari, ti sọ wipe ikọlu Boko Haram nilu Rann tipinlẹ Borno ti sọ ipinnu ijọba rẹ dotun lati sọ ikọ agbebọn naa ditan lai pẹ.

Ninu ọrọ to fi sọwọ si akanni opo Twitter rẹ, Aarẹ Buhari ba igbimọ isọkan agbayẹ ati awọn ajọ ti wọn ṣe iranwọ yoku nilu Rann kẹdun ikọlu naa.

Ṣugbọn ajọ awọn onisegun oyinbọ to n ṣe iranwọ ofẹ, MSF, ti da iṣẹ rẹ duro nilu naa lẹyin igba ti awọn agbebọn Boko Haram pa ẹniyan mọkanla.

Bakannaa ni ajọ isọkan agbaye gbe awọn oṣiṣẹ iranwọ rẹ jade kuro nilu naa.

Ikọlu Boko Haram n tun pọ si lẹnu ijọmẹta yii lẹyin igba ti awọn ologun Naijiria kede wipe wọn ti bori awọn agbebọn naa.

Image copyright Twitter/@Mbuhari