Kano: Omidan, rìn jáde láago mẹ́jọ alẹ́ ko rẹ́wọ̀n he

ile iṣẹ́ Hisbah
Àkọlé àwòrán,

Ọkan nínú àwọn ọmọbinrin tí wọn mú tó wà níbẹ̀ sàlàyé fún BBC pé òun jáde nílé láti lọ kí ọ̀rẹ́ oun ní

Omi tuntun ti rú, ẹja tuntun sì ti wọ̀ọ́ ní ìpínlẹ̀ Kano báyìí, túntun tó ṣẹlẹ̀ ní pé, ààyè kò si fún ọlọ́mọge láti jáde alẹ.

Yàtọ sí bí ǹkan ṣe rí ní àwọn ìpínlẹ̀ míràn tí ọmọ obìrin lè wọlé tàbí jáde ní àṣìkò tó bá wù wọn, ní ti ìpínlẹ̀ Kano, ọ̀tọ̀ lọmọ́ sorí o.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ṣọla Allyson: Obìnrin tí kò bá rẹwà ni yóò máa ṣí ara sílẹ̀

Gẹ́gẹ́ bí ofin Sharia tí ìpínlẹ̀ náà gùnlé, wọn ní gbogbo obìnrin tí ọlọ́pàá Hisbah bá ti mú ní ojú pópó pé ó ń dá rìn ní ààgo mẹ́jọ alẹ́ kìí ṣe ọmọ, yóò sì fí ojú ba àgọ́ ọlọ́pàá.

BBC sàbẹ̀wò sí ilé iṣẹ́ Hisbah lọ́jọ́rú láti rí àwọn ọmọbinrin kan tó ti ṣẹ̀ sí òfin yìí ní ọjọ́ ìṣẹ́gún, tí wọn sì sun ọgba Hisbah mójú.

Àkọlé àwòrán,

O jẹ́ ọkan lára ojúṣẹ́ Hisbah láti máa mú àwọn ọmọbinrin tó bá ń rìnrìn àrè kákìri ìlú, ó si ṣeéṣe kí wọn jẹ́ aṣẹ́wo

Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọpaa Hisbah ṣe sọ, oní nààbì ní àwọn ọmọbinrin yìí, tí wọn sì ń wa àwọn oníbara nínú iṣẹ́ wọn, sùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbinrin yìí ló sọ pe, ìdíkan tàbí òmíràn ló gbé àwọn jáde kúrò nílé ní àsìkò ti wọn mú àwọn.

Agbẹnusọ fún àjọ náà, Mallam Adamu Yahaya tó ba BBC sọ̀rọ́ sàlàyé pé, ó jẹ́ ọkan lára ojúṣẹ́ àwọn láti máa mú àwọn ọmọbinrin tó bá ń rìnrìn àrè kákìri ìlú, ó si ṣeéṣe kí wọn jẹ́ aṣẹ́wo.

Àkọlé àwòrán,

Ìpínlẹ̀ Kano: Ọmidan tó ba rín láago 8 alẹ́ yóò derò ẹwọn

Ó ní '' ojoojúmọ ní àwọn ọkùnrin máa ń jáde láti da ǹkan pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn yìí, tí a bá mú wọn, ti a sì rii dájú pé wọn kìí ṣe àṣẹ́wo, a ó fi wọn sílẹ̀ láti máa ba tiwọn lọ.

Ọkan nínú àwọn ọmọbinrin tí wọn mú tó wà níbẹ̀ sàlàyé fún BBC pé, òun jáde nílé láti lọ kí ọ̀rẹ́ oun ní ǹkan bíi ààgo mẹ́sàn alẹ́ ní àwọn Hisbah ba mú òun sínú motò wọn.

Wo aworan igbeyawo ọmọ gomina Ọyọ ati ti Kano

Oríṣun àwòrán, @GovKaduna

Àkọlé àwòrán,

Asiwaju Bọla Tinubu ati gomina Kaduna, Nasir El-Rufai jẹ diẹ lara awọn alejo ti wọn lọ si Kano fun igbeyawo naa

Ọmọ gomina ipinlẹ Ọyọ, Idris Abiọla, Ajimọbi ti gbe ọmọ gomina ipinlẹ Kano, Fatima Ganduje, niyawo lọjọ Abameta.

Ọlọkan-ojọkan alejọ pataki ni wọn kalẹ si ipinlẹ Kano nitori igbeyawo naa.

Sugbọn awọn ọmọ Naijiria kan koro oju si bi Aarẹ Muhammadu Buhari ti lọ sibi igbeyawo naa ti ko si lọ si ilu Dapbchi ti wọn ti ji awọn akẹkọbirin gbe.

Oríṣun àwòrán, @BuhariSallau

Àkọlé àwòrán,

Ninu awọn alejo ti wọn ti de ibi igbeyawo na ni Aarẹ Muhammadu Buhari ati awọn ọba-alade

Oríṣun àwòrán, @Dawisu

Àkọlé àwòrán,

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi lọ sibi igbeyawo naa pẹlu awọn gomina ẹgbẹ rẹ atawọn eeyan jankan-jankan miiran

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki

Àkọlé àwòrán,

Wọn ṣe igbeyawo naa loju awọn eeyan jankan-jankan ti wọn lọ sibẹ

Oríṣun àwòrán, GovKaduna

Àkọlé àwòrán,

Gomina ipinlẹ Eko, Akinwumi Amọde, ko gbeyin ninu awọn ti wọn lọ sibi igbeyawo naa ni Kano

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki

Àkọlé àwòrán,

Niwaju Aarẹ Muhammadu Buhari ni wọn ti ṣe igbeyawo naa