Fayose: Awọn to wa nijọba Buhari ko lee jẹ ki Boko Haram dẹkun

Gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayose Image copyright @GovAyoFayose
Àkọlé àwòrán Fayose ni ẹnu n kun awọn osisẹ ijọba Buhari lori ẹsun ijẹkujẹ

Gomina ipinlẹ Ekiti lẹkun iwọ oorun Naijiria, Ọgbẹni Ayọdele Fayose, ti ke gbajare sita wipe n se ni awọn oṣiṣẹ ijọba to wa lode bayii n lo anfani awọn ibudo ti awọn atipo ati awọn ti ogun le kaakiri lorilẹede Naijiria lati fi palẹ obitibiti owo ijọba mọ.

Gomina Fayose ni niwọn igbati owo ilu ba n tipasẹ awọn ibudo yii wọ apo awọn eeyan kan, ko lee si bi opin se lee de ba wahala Boko Haram lorilẹede Naijiria.

Gomina ipinlẹ Ekiti naa, ẹni to ti fi ọpọlọpọ igba lewaju awọn ipe to tako ijọba to wa lode bayii lorilẹede Naijiria ni lọdun to kọja ni ajọ to n tọpinpin iwa ibajẹ lagbaye, Transparency International kede wipe iwa ibajẹ ati ijẹkujẹ laarin ileesẹ ọmọogun orilẹede Naijiria n se ọpọlọpọ akoba fun akitiyan lati dẹkun gulegule ẹgbẹ agbesunmọmi Boko haram.

Fayose sọ wipe: "A ti gbọ iroyin awọn to n ko ounjẹ atawọn nkan arẹmọlẹkun gbogbo to wa fun awọn ibudo atipo ati awọn ti ogun le lẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria si orilẹede Chad ati Niger, bẹẹni nkan bii igba tọọnu eso ti orilẹede Saudi Arabia gbe kalẹ f'awọn ibudo awọn atipo ati awọn ti ogun le ni wọn ti n ta kaakiri ọja nilu Abuja."

Gomina ipinlẹ Ekiti naa sọ wipe asiko to fun Aarẹ Buhari lati pakiti mọra se afọmọ ijọba rẹ ki o si yọ gbogbo awọn to n fi wahala Boko Haram jẹun ninu ijọba danu bi ẹni yọ jiga iyẹn to ba jẹ lootọ lo n fẹ ki gulegule awọn Boko Haram o dopin.