Ijọba ipinlẹ Ọyọ yoo satunse si ọdun egungun

Egungun n le awọn eeyan kan Image copyright NAIJ.com
Àkọlé àwòrán Wahala ati rogbodiyan lasiko ọdun egungun wọpọ kaakiri ipinlẹ Ọyọ.

Ijọba ipinlẹ Ọyọ, lẹkun iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria, ti sọ wi pe igbesẹ ti wa nilẹ lati dẹkun wahala ati rogbodiyan to maa n fi igbagbogbo waye lasiko ọdun egungun nipinlẹ Ọyọ.

Kiise iroyin mọ wi pe oniruru rogbodiyan lo maa n waye lasiko ọdun egungun ni ilu Ibadan atawọn ilu miran kaakiri ipinlẹ Ọyọ.

Kọmisọna feto iroyin, asa ati irinajo afẹ nipinlẹ nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Toye Arulogun, salaye nibi ipade to se pẹlawọn alagbaa ati awọn aarẹ isẹse kaakiri ipinlẹ naa nilu ibadan wipe ijọba to wa lode nipinlẹ naa ko ni faaye gba rogbodiyan lasiko ọdun egungun mọ.

O ni ohun ti ijọba n fẹ lati maa gbe larugẹ ni awọn ayẹyẹ, asa, isẹse to rọ mọ ọdun egungun bii ti igba iwasẹ.

Ọgbẹni Arulogun woye wipe, "ara awọn ajogunba iṣẹsṣe ati ọdun abalaye ni ọdun egungun jẹ eleyi ti ileesẹ ijọba ti pinnu lati gbe larugẹ lọna ti ko la wahala ati rogbodiyan lọ."

Image copyright NAIJ.com
Àkọlé àwòrán Gbajugbaja lọdun egungun ni ilẹ Yoruba

Kọmisọna ọhun wa tun fi kun un wipe ijọba ti bẹrẹ ifikunluku pẹlu awọn alẹnulọrọ lati rii pe ọdun egungun bọ si ipo gbajugbaja to yẹ ẹ.

Kini amọran awọn asiwaju ọdun egungun nipinlẹ Ọyọ?

Ninu ọrọ rẹ, olori alagbaa nilu Ibadan, Oloye Ọjẹtunde Akinlẹyẹ Asoleke, ni gbogbo awọn ọlọdun iṣẹṣe lo ti setan bayii lati darapọ mọ igbesẹ ijọba lati ṣe afọmọ ilana ọdun egungun lọna ti ko ni mu wahala lọwọ mọ.

Olori alagbaa ilu Ibadan tun mu aba jade fun fifofinde egungun to ba fa walaha fun ọdun mẹta ki irufẹ egungun bẹẹ o maa sẹyọ mọ.

Oloye ni awọn asiwaju agboole egungun gbogbo ti n nda awọn egungun wọn lẹkọ lori ihuwasi ọmọluwabi lasiko ọdun egungun.

Ninu ọrọ tirẹ, aarẹ isẹmbaye lagbegbe Saki, Oloye Sẹsan Onibode, ni asiko to fun atunse ọdun egungun ti yoo mu eto aabo to daju waye fun un ati wipe yoo si tun jẹ ki alaafia o jọba lawọn ajọdun agboole sagboole.