EFCC fẹ gbegidina ibo rira saaju ibo 2019

Alaga EFCC, Ibrahim Magu Image copyright EFCC

Alaga ajọ EFCC to n gbogun tiwa ibajẹ, Ibrahim Magu, ti pinnu lati gbegi dina ibo rira nibi ipade awọn asoju ẹgbe oselu saaju ki wọn o to fa ọmọ ẹgbẹ kale fun ibo gbogbogbo ti ọdun 2019.

Alaga naa si sọ wipe ajọ rẹ ko ni gba fun awọn oloṣelu lati ra ibo nigba ibo gbogbogbo lọdun 2019.

Nigba to n sọrọ lori eto 'Question Time' lori amohumọworan Channels, Magu sọ wipe EFCC n ba ajọ INEC to n ṣe eto ibo ni Naijiria ṣiṣẹ nitori ati di gbogbo ọna ti awọ eeyan le gba lati gbe owo pipọ kaakiri yala owo kisi ni tabi lọna ile-ifowopamọsi.

Magu sọ wipe: "A o gbegidina rira ibo fun awọn eeyan tabi lilo owo nigba ipade awọn ẹgbe oṣelu. Ati gbe eto ati ṣe bẹ silẹ."

O ti pẹ ti iroyin rira ibo ti maa n doyika ibo ni Naijiria.

Image copyright EFCC

Sugbọn ko ti si aridaju lori boya ajọ EFCC ni agbara ati mojuto bi awọn ẹgbẹ oṣelu ṣe n nawo wọn ninu iwe ofin Naijiria.