Okunrounmu on Buhari's government: Kò jọ pé àwọn èèyàn ń ṣa oúnjẹ jẹ lórí àkìtàn jẹ ní ìjọba rẹ

Okunrounmu on Buhari's government: Kò jọ pé àwọn èèyàn ń ṣa oúnjẹ jẹ lórí àkìtàn jẹ ní ìjọba rẹ

Sẹnetọ orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Femi Okunrounmu ti sọ wipe ijiya Ọlọrun ni ijọba Buhari jẹ fun ọmọ Naijiria ati wipe Buhari ko mọ nkankan nipa eto ọrọ aje.

O ba BBC Yoruba sọrọ lori ipo ti Naijiria wa lonii pẹlu gbogbo ohun ti orilẹede naa n kọju o si gbee lẹgbẹ kẹgbẹẹ awọn ileri ti aarẹ Muhammadu Buhari ṣe fun awọn ọmọ Naijiria nigba ti wọn dibo yan an wọle.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si:

"Láti ọjọ tí Nàìjíríà tí ń ní ìjọba, mi ò rí èyí tó burú tó ti Buhari rí. Kò jọ pé àwọn èèyàn ń ṣa oúnjẹ jẹ lórí àkìtàn bó tilẹ̀ jẹ́ pé ebi ń pa àwọn èèyàn gan lágbàáyé".

O ni olè ni gbogbo àwọn sẹ́nétọ̀ ń jà l'Abuja báyii.

Alagba Okunrounmu ni ṣe ni eto ọrọ aje wa n buru sii ti aarẹ to wa lori oye ko si mọ nkankan nipa ọrọ aje rara.