Osun Election 2018: INEC pàrokò ìkìlọ̀ ránṣẹ́ s'áwọn olóṣèlú tó fẹ́ ràbò

Awọn osisẹ ajọ Inec

Àjọ eleto idibo lorilede Naijiria ti paroko ikilọ ranṣẹ s'awọn oloselu pe, ko saaye ati ra ibo tabi ta ibo lasiko idibo sipo gomina nipinle Ọsun, eyi ti yoo waye ni ọjọ abamẹta.

Alakoso ajọ INEC nipinlẹ osun Olusegun Agbaje salaye fún ikọ BBC Yoruba pe, ikoko ko ni gbẹyin ko tun gba ṣọṣọ ni ọrọ ibo rira ati àjọ naa.

"A ko lee gba ki awọn obayejẹ ẹda kan maa fi tiwọn ko ba ilakaka ajọ INEC at'awọn agbofinro."

Àkọlé fídíò,

Osun Election 2018: Aráàlú ní àwọn kò fẹ́ ìjọba elébi mọ́

Ọgbẹni agbaje tun ṣalaye pe, awon ẹrọ idibo ti wọn yoo lo fun eto idibo ọjọ abamẹta yoo yatọ s'awọn ti wọn ti nlo bọ tẹlẹ.Ọ ni ajọ naa ti mura de awọn to lee fẹ sọ ibo di káràkátà ati pe nnkan yoo yàtọ̀ sí èyí tó wáyé ni ìpínlẹ̀ Èkìtì.

Bakan naa, awọn aja ọlọpaa afimufinlẹ̀ ati ikọ to n koju ado oloro wa lara awọn agbofinro ti yoo pese aabo ni idibo ọjọ Abamẹta ni Ọṣun.

Igbakeji oga ọlọpaa patapata, Habila Joshak, ti o n dari gbogbo agbofinro fun idibo naa lo sọ bẹẹ ni Osogbo lọjọ Eti.

Àkọlé fídíò,

Ọ̀ṣun Oṣogbo 2018: Ulrich Salazar wálé ọdún láti New York

Joshak ni, bo tilẹ jẹ pe agbegbe alaafia ni Ipinlẹ Ọṣun ikọ ọlọpaa to n koju iwa ipa ni kiakia, ti wa ni ikalẹ lati pana wahala to ba fẹ yọ̀ju.O ni gbogbo awọn agbegbe to ṣeeṣe ki wahala wa, ni awọn ọlọpaa yoo maa rin kakakiri lati ri pe ko si ẹnikẹni ti awọn janduku da laamu.Joshak sọ pe, "Mo mọ wipe awọn oloṣelu kan ti le mura lati da oju eto idibo yi ru, a o da sẹria fun wọn. Ṣugbon, a ko ni dun kuku mọ ẹnikẹni ti ko ba fa wahala kankan.

"Ni awọn agbegbe ori omi, to ba sun mọ Ipinlẹ Ọsun, ọkọ ofurufu ati awọ̀n ọkọ oju omi ni a o lo lati pese aabọ."Ẹgbẹrun lọna mejidinlọgbọn ni gbogbo agbofinro ti yoo pese abo ni idibo ọjọ abamẹta.

Inec fa orukọ olutọpinpin ibo latilẹ okeere mọkandinlọgọrun yọ

Awọn ọmọ ilẹ okeere mọkandinlọọdunrun ni ajọ to n mojuto eto ibo lorilẹede Naijiria, INEC ti fa orukọ wọn yọ kuro ninu iwe oludibo orilẹede yii.

Eyi wa lara igbesẹ ti ajọ naa n gbe lati dẹkun awọn aleebu to n f'arahan lori iwe oludibo orilẹede Naijiria.

Gẹgẹbi alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ṣe sọ, awọn ajeji naa f'orukọ silẹ pẹlu awọn ayalo orukọ to f'arajọ orukọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @inecnigeria

Àkọlé àwòrán,

Ajọ INEC ni ajọ naa nilo ifọwọsowọpọ awọn lajọlajọ ijọba gbogbo lati mu ki ilana idibo o kẹsẹ jari

Awọn eeyan naa lo ni wọn parọ fun awọn osisẹ ajọ naa to seto idibo lagbegbe wọn sugbọn ti ayẹwo igbalode lori iwe idibo ilẹ Naijiria ti fihan gbangba pe aare ni wọn jẹ, wọn kii se ọmọ orilẹede Naijiria.

Ọjọgbọn Yakubu ni ajọsepọ to waye laarin ajọ naa ati ileesẹ to n mojuto iwọle-wọde lorilẹede Naijiria lo mu ko seese fun ajọ naa lati sisọ loju eegun awọn eeyan naa.

Alaga ajọ INEC ni ipa gbogbo to ba yẹ ni ajọ naa yoo sa lati rii wi pe eto ati ilana idibo lorilẹede Naijiria dan mọran ju ti atẹyinwa lọ.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: