Fayose we lawani ni ilu Gombe

Gomina fayose pẹlu awọn gomina lẹgbẹ oselu PDP Image copyright @GovAyoFayose
Àkọlé àwòrán Ọkan lara awọn ohun to goke ju laarin awọn ẹgbẹ alatako lorilẹede Naijiria ni Fayose jẹ

Ko si ariyanjiyan wipe ọkan gboogi lara awọn ohun alatako si ijọba to wa lode bayii ni orilẹede Naijiria ni Ayọdele Fayose.

Fayose ni gomina ipinlẹ Ekiti ni ẹkun iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria.

Oniruuru ara si ni Fayose ti da lọna ati pe akiyesi si awọn ero rẹ nipa isejọba Muhammadu Buhari.

Lawani ni Fayose tun we ni ilu Gombe, lẹkun ariwa orilẹede Naijiria, nibi ipade awọn gomina to wa labẹ ẹgbẹ oselu PDP lorilẹede naa.

Image copyright @GovAyoFayose
Àkọlé àwòrán Oniruuru ara ni Fayose ti da lati pe akiyesi si awọn ero rẹ
Image copyright @GovAyoFayose
Àkọlé àwòrán Se ara ifidimulẹ isọkan ninu ẹsin leyi ni tabi ara ọgbọn oselu lorilẹede Naijiria?

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: