Igbẹjọ Eni, Shell yoo tẹsiwaju lọjọ kẹrinla oṣu kẹta

Ami idanimọ ileesẹ Eni ati Shell Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Eni ni awọn ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn

Igbẹjọ awọn ileesẹ ipọnpo nlanla meji, Eni ati Shell to yẹ ko wa ye loni tẹlẹ ni wọn ti sun siwaju bayii.

Awọn ileesẹ ipọnpo meji yii njẹjọ lori ẹsun pe wọn lọwọ ninu iwa kotọ ninu idokoowo wọn lori ibudo ipọnpo kan lorilẹede Naijiria.

Nibayii, ọjọ kẹrinla oṣu karun ni igbẹjọ naa yoo maa waye bayii gẹgẹbii adajọ to n gbọ ẹjọ naa nilu Milan ṣe sọ.

Adajọ naa tun sọ wi pe wọn yoo taari ẹjọ naa si ọdọ adajọ miran nitori awọn igbẹjọ to pọ ni iwaju oun ki igbẹjọ naa maa baa falẹ.

Àkọlé àwòrán Awọn ọmọ Naijiria pẹlu lọwọ ninu ọrọ naa

Awọn ileeṣẹ apọnpo rọbi nlanla meji yii n jẹjọ lori ẹsunfifunni lowo riba, ati iwa ijẹkujẹ lasiko ti wọn fẹ fi ra oko ipọnpo kan lorilẹede Naijiria.

Awọn amofin ijọba orilẹede Italy n fi ẹsun riba sisan kan awọn ileeṣẹ mejeeji nigba ti wọn fẹ ra kọnga ifapo OPL 245, to wa lori omi orilẹede Naijiria eyi ti wọn ni o n gbọn biliọnu mẹsan agba epo jade ti owo rẹ din diẹ ni ẹẹdẹgbẹta biliọnu naira.

Amọṣa, awọn ileeṣẹ elepo rọbi mejeeji yii ni wọn ti ṣ'alaye wi pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn n fi kan wọn yii.

Ninu atẹjade kan to fi s'ita, ileeṣẹ ipọnpo rọbi Eni ni o da awọn loju wipe eto idajọ yoo fi idi ootọ mulẹ wipe ọwọ awọn mọ.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: