Sẹnatọ Sani n fẹ ki Buhari ṣiṣẹ lori isinku ọwọọwọ ni Naijiria

Shehu Sani, asofin agba orilẹede Naijiria Image copyright @ShehuSani
Àkọlé àwòrán Ọpọ isẹlẹ ikọlu ati ipaniyan lo n waye kaakiri awọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria

Aṣofin agba kan lati ẹkun ariwa orilẹede Naijiria, Shehu Sani ti sọ wi pe erongba ati pa awọn ẹya kan run patapata ti n se kẹrẹkẹrẹ wọ orilẹede Naijiria.

Sẹnatọ Sani ni ipaniyan to waye lagbegbe Mambila jẹ ohun to buru pupọ ti ko si yẹ ni gbigbọ laarin awọn eeyan orilẹede Naijiria.

Sẹnatọ Sani ni orilẹede Naijiria ti di orilẹede ti n fi igbagbogbo ṣe isinku eleyi to ni ijọba gbọdọ dide lati gbogun ti iku ọwọọwọ to n ṣẹlẹ lorilẹede Naijiria.

O ni asiko yii kọ ni o yẹ fun araalu lati korira tabi fẹran ijọba atawọn ileeṣẹ alaabo gbogbo bikoṣe lati di wọn mu ki wọn si wa jẹjọ lori ẹmi gbogbo ti o n sọnu ti wọn si n dero ọsan gangan.

Bakanna lo tun ke si aarẹ muhammadu Buhari ti orilẹede Naijiria lati maṣe ko ọrọ awọn to npe e lati ṣe abẹwo si Dapchi ati Benue danu nitori wọn woye wipe o yẹ ki aarẹ fi ara rẹ han gẹgẹbii aṣiwaju lasiko ti awọn eeyan kan wa ninu ipayinkeke ni.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: