Buhari yoo ṣ'abẹwo oju mi to o s'awọn ipinlẹ ti ikọlu ti waye

Aare Buhari Image copyright @BashirAhmaad
Àkọlé àwòrán Oniruuru awuyewuye lo ti waye lori kikuna ti aarẹ Buhari kuna lati yọju si awọn agbegbe ti ikọlu ti waye kaakiri orilẹede Naijiria

Aarẹ Buhari yoo bẹrẹ abẹwo si awọn ipinlẹ ti ina ikọlu ti waye eleyi to gbẹmi awọn eeyan laipẹ yii kaakiri lorilẹede Naijiria.

Oniruuru awuyewuye lo ti waye lori kikuna ti aarẹ Buhari kuna lati yọju si awọn agbegbe ti ikọlu ti waye kaakiri orilẹede Naijiria.

Atẹjade kan eleyi ti olubadamọran pataki fun aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin ati ipolongo, Fẹmi Adesina fi sita, awọn akojọpọ iwadi lori awọn isẹlẹ to sẹ wọnyii, eleyi ti aarẹ Buhari pasẹ fun awọn ileesẹ ọmọogun lati se lo faa ti aarẹ si fi dẹsẹ duro di akoko yii ki o to se awọn abẹwo oju mi to o si awọn ilu ati ipinlẹ ti ọrọ kan.

Atẹjade ọhun ni ojoojumọ ni aarẹ orilẹede Naijiria n gba aabọ latọdọ awọn asaaju ileesẹ ọmọogun loriẹede yii ti o si n fi bi nkan se n lọ si to awọn gomina ipinlẹ naa leti.

Image copyright @BashirAhmaad
Àkọlé àwòrán Buhari yoo ṣ'abẹwo si Tabara, Benue

Aarẹ Buhari rọ awọn olugbe agbegbe ti isẹlẹ laabi naa ti sẹlẹ lati fi ọwọ sowọps pẹlu awsn osisẹ alaabo lọna ati lee tete dẹkun awọn isẹlẹ ibi naa ki wọn si lee fi awọn ti aje rẹ ba simọ lori jofin.

Atẹjade naa tun sọọ di mimọ wi pe bẹrẹ lati ọjọ aje ọjọ karun osu kẹta, aarẹ Muhammadu Buhari yoo bẹrẹ abẹwo si ipinlẹ Taraba, lẹyin eyi ni yoo si tun lọ si ipinlẹ Benue, Yobe, Zamfara ati ipinlẹ Zamfara.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: