Ibo Sierra Leone: Awọn alabojuto ibo pinu ibo to yanranti

Aworan awọn alabojuto ibo Image copyright ECONEC/Paul Ejime
Àkọlé àwòrán Iṣẹ nla wa ni iwaju awọn aarẹ naa lati ri ki eto idibo lo ni rọwọ n rọ sẹ

Awọn olori ikọ alabojuto ibo ti ṣe'pade ni olu ilu Sierra Leone, Freetown lati ṣe agbekalẹ eto to yaranti fun eto idibo ni orilẹede naa.

Ajọ Ecowas ati ajọ iṣọkan ilẹ Afrika, (AU) lo ṣagbatẹru ipade naa eleyi ti aarẹ fidihẹ igba kan ri lorilẹede Liberia, ọjọgbọn Amos Sawyer ṣ'oju Ecowas, ti aarẹ ana lorilẹede South Africa Kgalema Motlanthe si ṣoju AU.

Atẹjade kan ti Paul Ejime, agbẹnusọ fun agbarijọpọ awọn eleto idibo nilẹ Afrika, Econec, fi ṣọwọ si awọn oniroyin ni aarẹ Ghana tẹlẹri John Mahama ṣoju ajọ Commonwealth ti aarẹ ana orilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan si ṣoju ibudo iwadi lori ifidimulẹ eto oṣelu arawa nilẹ Afrika nibi ipade naa.

Ninu abajade ipade naa, wọn sọ wi pe aṣeyọri eto idibo nilẹ Sierra Leone rọ mọ ki awọn ara ilu gaan kopa lati mu ki eto naa lo ni irọwọ rọ sẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ololufẹ ẹgbẹ oṣelu Sierra Leone kan nibi ipolongo ibo

Wọn fi kun pe awọn olori iko alabojuto ibo to wa nilẹ koni gbe lẹyin ẹnikankan bi ki se lati ri wi pe gbogbo nkan lo leto ninu eto idibo to'n bo lọna.

Lọjọ keje osu yi ni orilẹẹde Sierra Leone yoo dibo lati yan Aarẹ tuntun,awọn asoju ile igbimo asofin ati ibo ijọba ibile.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: