O dun yin pe ọmọ Yoruba ko gba Oscars abi?

Guillermo del Toro ati Frances McDormand Image copyright Getty Images/Reuters

Ami ẹyẹ Oscars waye mọju oni. Bi o tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ wọn ko ni ayẹsi nibi ayẹyẹ, awa yoo ṣe afihan diẹ lara awọn ọmọ orilẹede yi paapa julọ awọn ti wọn je ọmọ kaaro o jiire ti wọn nṣe gudugudu meje yaya mẹfa ni Hollywood.

David Oyelowo:

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán David Oyelowo wo Dashiki nibi afihan sinima Black Panther

Oxford nilu ọba ni wọn ti bi David Oyelowo.

Nigba to pe ọmọ ọdun mẹfa, awọn obi rẹ ko lọ si ilu Eko nibi ti baba rẹ ti ṣiṣẹ pẹlu ile ọkọ ofurufu orilẹede Naijiria ti Mama rẹ si ba ile isẹ ọkọ oju irin ṣiṣẹ.

Oyelowo jẹ ilumọka oṣere sinima to kopa ninu awọn sinima bi Selma (2014), The Butler (2013), The Last King of Scotland (2006) ati Queen of Katwe (2016).

Adewale Akinnuoye-Agbaje:

Image copyright Twitter/Adewale
Àkọlé àwòrán O le so ede Yoruba, Geesi, Italian ati Swahili.

Wọn fi igba kan sọ wipe ohun ni yoo kopa gẹgẹ bi T'Challa ninu ere sinima, Black Panther to gbode kan bayi.

Ninu awọn to kopa ni Hollywood to si jẹ ọmọ kaaro o jiire, ogbontarigi ni Adewale Akinnuoye-Agbaje.

Wọn bii lọjọ kejilelogun oṣu kẹjo ọdun 1967, ni Washington, D.C.

Ọmọ Yoruba lati ipinle Ogun lawọn obi rẹ.

O ti kopa ninu awọn ere bii: The Bourne Identity, G.I. Joe: The Rise of Cobra, The Mummy Returns ati Suicide Squad.

Adepero Oduye:

Image copyright Twitter/Adepero Oduye
Àkọlé àwòrán O je ọkan lara awọn ọmọ meje ti awọn obi rẹ bi.

Brooklyn, New York ni wọn ti bi Adepero Oduye.

Ohun ati Chiwetel Ejiofor jọ kopa ninu ere Steve McQueen, 12 Years a Slave, to gba ami ẹyẹ Oscars fun aworan to dara ju lọdun 2014.

Bakanna lo le ti ri ri ninu Steel Magnolia ati Pariah.

John Adedayo Adegboyega:

Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Boyega ni inu ohun dun lati pada wale nigba ti o wa si Naijiria lọdun kerẹsi to kọja

Abigail ọmọ Aboderin ati Samson Adegboyega lorukọ awọn obi rẹ.

Oniwasu ni Baba rẹ, o si wu ki ọmọ rẹ naa tẹle ipasẹ rẹ.

Sugbọn ere ori itage ni John Adedayo B. Adegboyega ti ọpọ mọ si John Boyega yan laayo.

Loni o ti gbe orukọ ẹbi rẹ ga.

Laipẹ yi o si wa si Naijiria nibi to ti ni ohun n wa iyawo.

Morenike Balogun:

Image copyright Twitter/Morenike Balogun
Àkọlé àwòrán Morenike Balogun pelu awọn osere inu ere alabala ''How to get Away with Murder''

Morenike Balogun kii ṣe oju ti ọpọ ẹniyan mọ sugbọn iṣẹ ọwọ rẹ nipa kikọ itan fun awọn ere ori amohunmaworan jẹki o ta awọn akẹgbẹ rẹ yọ.

Orilẹede Amerika ni wọn ti bii, o si kawe gboye nipa imọ ere ori itage lati ile ẹko Dartmouth College.

Bi o ba ma'n gbadun ere alabala ti orukọ rẹ njẹ ''How to Get away with Murder,'' Morenike wa lara awọn ti wọn ma'n kọ itan fun ere naa.

Ọpọ lo ti'n kan sara sii fun iṣẹ ọwọ rẹ.

Hugo Weaving:

Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Bawo loyinbo ṣe jẹ ọmọ Yoruba?

O ya yin lẹnu bii?

Bi a ba fi ibi ti wọn bi si tọọ, ojulowo ọmọ Ibadan ni Hugo Weaving gbọdọ jẹ.

Lọdun ti Naijiria gba ominira ni wọn bii si ile iwosan ikọṣẹ iṣegun, UITH nilu Ibadan.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: