Aare orilẹede Naijiria gbalejo aarẹ Liberia, George Weah.

aworan aare George Weah ati aare Muhammadu Buhari Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Igba akọkọ ni yii ti aarẹ Weah yoo wa si orilẹede Naijiria leyin iburawole re

Aarẹ Muhammadu Buhari ti gbalejo aarẹ tuntun orilẹede Liberia, George Weah ni ọọfisi aarẹ to wa ni olu ilu orilẹede Naijiria, Abuja.

Iroyin sọwipe awọn ọkọ ayọkẹlẹ to tẹle aarẹ Liberia lọwọọwọ de ọọfisi aarẹ Buhari l'agogo mejila aabọ ọsan ọjọ Aje.

Awọn olori orilẹede mejeeji naa se ipade ikọkọ ni ọọfisi aarẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOkunrounmu: Ijọba Buhari jẹ ijiya Ọlọrun fun Naijiria

Abẹwọ ọjọ Aje naa jẹ igba akọkọ ti aarẹ Weah yoo wa si orilẹede Naijiria, lẹyin ti wọn bura fun gẹgẹ bi aarẹ Liberia l'ọjọ Kejilelogun osu Kini, ọdun 2018.

Weah jawe olubori nigba to bori aarẹ tẹlẹri, Joseph Kabila ti ẹgbẹ oselu, Unity Party, nigba ti oun jade labẹ ẹgbẹ oselu Coalition for Democratic Change.

Ibura wọle aarẹ Weah ni ipilẹsẹ igba akọkọ ti orilẹede Liberia yoo yan adari eto iṣejọba awaarawa pẹlu ibo ida ọgọta awọn ọmọ orilẹede naa.

Related Topics