Bukola Saraki pe fun ajọṣepọ laarin Ghana ati Naijiria

Ọmọ Ghana to nse ajọdun (Fọto atijọ) Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Orilẹede Naijiria ati Ghana ni ajọsepọ to fidi mulẹ

Aarẹ ileegbimọ aṣofin agba lorilẹede Naijiria, Sẹnatọ Bukọla Saraki ti pe fun ajọṣepọ to gboopọn sii laarin awọn orilẹede lẹkun iwọoorun Afirika lati lee ṣi ilẹkun igba ọtun fun ilẹ Afirika.

Sẹnatọ Saraki, ni oniruuru abajade iwadi lo n fidi rẹ mulẹ wipe nkan o ọjọ iwaju ilẹ Afirika ni ifọwọsowọpọ awọn eniyan rẹ, paapaa julọ lati lee ṣ'eto ọjọ ọla to gun rege fun awọn ọdọ.

Aarẹ ileegbimọ orilẹede Naijiria ṣalaye ọrọ yii lasiko to fi n gbe idanilẹkọ kan kalẹ lorilẹede Ghana lati sami ayẹyẹ ọdun mẹwa ọtọọtọ laisi idaduro ti ileegbimọ aṣofin orilẹede Ghana ti nṣiṣẹ.

O wa pe fun idasilẹ igbimọ apero kan laarin awọn ileegbimọ aṣofin orilẹede mejeeji lati lee ṣe agbedide igba ọtun fun ẹkun naa ati ilẹ Afirika lapapọ.

Sẹnatọ Saraki ni ara ohun ti igbimọ apero naa yoo lee ṣiṣẹ le lori ni mimu ayipada baa bi awọn ọdọ ṣe n sa fi ilẹ baba wọn silẹ lọ soke okun ti wọn si n tipasẹ bẹẹ kagbako iku wọn.

"Laarin awọn to n ṣatipo lorilẹede Libya bayii, o diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọgọta lo jẹ ọmọ orilẹede Ghana ti ẹgbẹrun marundinlaadọta si wa lati orilẹede Naijiria. Awọn ọdọ wa ko ri ọjọ ọla ti o dara ni ilẹ baba wọn, idi si niyi ti wọn fi n sare gba oke okun lọ. Gẹgẹbii aṣiwaju to dara, ẹtọ ọ wa ni lati rii daju wi pe anfani ati j'eeyan wa nilẹ fun wọn nilẹ baba wọn."

Saraki tun ṣalaye siwaju sii wi pe ohun to ṣokunfa osi ati aini ni ilẹ Afirika ko ṣẹyin bi awọn orilẹede Afirika ṣe sọ ara wọn di orilẹede to n pese ohun eelo fun agbaye.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: