Ondo: Sísá Gààrí síta ń fa àtúnṣẹ̀ àrùn ibàa Lassa

Gaari ti wọn n ta lori atẹ

Oríṣun àwòrán, Twipu.com

Àkọlé àwòrán,

Awọn gaari ti wọn n da silẹ lo n fa eku to ni aisan lassa lati tọ si ori garri yii, eleyi ti yoo fa aarun Lassa fun gbogbo ẹni to ba jẹ garri naa

Ijọba ipinlẹ Ondo tun ti kesi awọn araalu ati awọn to n se garri, lati sọra fun aṣa sisa gaari sita ni ilẹ lasan.

Kọmisọnna fun ọrọ ilera, Wahab Adegbẹnro lo ke gbajare naa lasiko ti iroyin jade wi pe Lassa Fever tun ti pa eniyan kan ni ipinlẹ Ondo.

Adegbenro ni awọn to n sa gaari silẹ n fayegba eku to ni aisan lassa lati tọ si ori garri yii, eleyi ti yoo fa aarun Lassa fun gbogbo ẹni to ba jẹ garri naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Adedoyin: Tí mo bá rí Buhari, màá sọ fun kó rántí pé Ọlọ́run wà

Ninu ọrọ rẹ, imọtoto pẹlu ounjẹ jijẹ se koko, nitori awọn to ba fi ọwọ kan awọn to ni aisan lassa naa le ko aaarun naa.

Adegbenro ni arun yii ti di itankalẹ aarun nitori pe ọdọọdun ni iba Lassa yii ma n waye ni agbeegbe ijọba ibilẹ mẹta nipinlẹ naa.

Awọn ijọba ibilẹ naa ni Ọwọ, Ọsẹ ati Iwo Oorun guusu Akoko.

Oríṣun àwòrán, Science Photo Library

O fikun wi pe, ijọba ipinlẹ Ondo n se itọju awọn ti wọn ko aarun naa ni ile iwosan ijọba ti FMC Ọwọ, ati wi pe, itankalẹ aarun naa ko i tii kọja agbara awọn.

Kọmisọnna fun eto ilera naa wa parọwa fun awọn to n se garri lati ma a yan lori ina , ki o gbe daradara ko o to di wi pe wọn yoo ma a ta a fun awọn eniyan.

Lassa fever: NCDC késí aráàlú láti máa se ìmọ́tótó

Imọtoto bori aarun mọlẹ, bi ọyẹ ti n bori oru, ajọ to n gbogun ti aisan lorilẹede Naijiria(NCDC) ti parọwa fun awọn eeyan lati mu imọtoto lọkunkundun lẹyin ti eeyan kan padanu ẹmi rẹ ninu awọn meji ti wọn lugbadi aarun ọhun.

Ajọ NCDC ṣalaye pe Ipinlẹ Ondo ati Edo ni aarun naa tun ti jẹyọ.

Ajọ naa ni o bani ninu jẹ pe aarun iba lassa ko ti i di ohun igbagbe pẹli akitiyan ijọba apapọ lati ri i wi pe aarun naa ati iba pọnju kasẹ nlẹ ni Niaijiria.

Oríṣun àwòrán, Press Association

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọjọ ori ti aarun naa n damu julọ ni ni ọdun mọkandinlogun si ogoji ọdun

Iwadi ajọ naa fihan pe eeyan to le ni ẹgbẹrun mẹta lo ti lugbadi aarun iba lassa ni ipinlẹ mejilelogun lati oṣun kinni titi di oṣu kọkanla ọdun yii.

Ajọ naa fidi rẹ mulẹ pe ida mẹrindinlaadọta ninu ọgọrun awọn eeyan to lugbadi aarun naa lọdun yii lo wa lati ipinlẹ Edo nigba ti ida mẹrinlelogun si wa lati Ondo

Eeyan marundinlogoji miran ko aarun iba Lassa ni ipinlẹ mẹfa

Ajọ to n mojuto ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC ti kede wi pe eeyan marundinlogoji miran lo tun ti ko aarun iba Lassa lawọn ipinlẹ marun laarin ọjọ kẹrindinlọgbọ oṣu keji ọdun 2018 si ọjọ kẹrin oṣu kẹrin ọdun 2018 kanna.

Ninu atẹjade rẹ fun ọsẹ kẹsan ninu ọdun lo ti gbe eyi jade.

Gẹgẹbii ajọ to n mojuto ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria naa se sọ, awọn ipinlẹ ti eeyan marundinlogoji naa ti ṣẹyọ ni ipinlẹ Edo pẹlu eeyan mọkandinlogun.

Oríṣun àwòrán, Corbis Royalty free

Ipinlẹ Ondo pẹlu eeyan marun, ipinlẹ Bauchi pẹlu eeyan kan, ipinlẹ Ebonyi pẹlu eeyan mẹsan, ti eeyan kan si tun ti ni aarun iba lassa naa ni ipinlẹ Plateau pẹlu.

Pẹlu abajade tuntun yii, o ti le ni ẹgbẹrun kan ati ọgọfa aisan ti wọn funrasi gẹgẹbii iba Lassa to ti waye lorilẹede Naijiria, ọtalelọọdunrun o din mẹta ninu wọn ni wọn ti fidi rẹ mulẹ nigba ti wọn tun fidi ẹẹdẹgbẹrin o le ogun ati mẹta mulẹ wi pe wọn kii ṣe arun ọhun.

Koko nipa ajakalẹ arun iba Lassa lorilẹede Naijiria

  • Awọn ọjọ ori ti aarun naa n damu julọ ni ni ọdun mọkandinlogun si ogoji ọdun.
  • Awọn oṣiṣẹ eleto ilera meji f'ara kaasa aarun iba lassa naa laarin ọjọ kẹrindinlọgbọ osu keji ọdun 2018 si ọjọ kẹrin osu kẹrin ọdun 2018 nipinlẹ Ebonyi.
  • Nibayii, o ti di osisẹ eleto ilera mẹfa lo ti lugbadi aarun yii kaakiri awọn ipinlẹ ipinlẹ mẹfa-Ebonyi, Benue, Nasarawa, Kogi, Ondo ati Edo.
  • Awọn ipinlẹ ti ọwọja arun iba lassa ti wọpọ ju lọ ni Edo, Ondo ati Ebonyi.

Nibayii, ipinlẹ mejidinlogun ni ọwọja aarun lassa ti ja de lorilẹede Naijiria bayii; bẹẹni aadọfa eeyan lo ti ran lọ sọrun.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Awọn eniyan marundinlaadọta ti salaisi latari arun iba-pọnju, pọntọ.

Bakanna ni ajọ naa tun ṣalaye wipe oun ti fi ikọ awọn akọṣẹmọṣẹ ranṣẹ si awọn ipinlẹ lo mu ile ti orilẹede Benin Repubublic, iyẹn awọn ipinlẹ bii Kebbi, Kwara, Niger ati Ọyọ lati tubọ ṣeto amojuto to yẹ fun awọn agbegbe naa.

O tẹsiwaju, o ni ajọ ilera agbaye, WHO ti n fọwọsowọpọ pẹlu orilẹede Naijiria lati rii daju wi pe wọn wa'wọ aarun naa bọlẹ laipẹ ọjọ.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: