Aarẹ Buhari ni ifọwọsowọpọ lo le mu alaafia j'ọba

Aare Buhari Image copyright @MBuhari
Àkọlé àwòrán Aare Buhari pe fun ibagbepo lalafia ni Taraba

Aarẹ orilẹẹde Naijiria Muhammadu Buhari ti kesi awọn ọmọ orilẹẹde yi lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn eleto aabo ki wọn baa le dẹkun ọwọja iwa ọdaran to gbalẹ kan.

O ni eleyi ṣe pataki paapaa julọ f'awọn to wa ni agbegbe ibi ti ikọlu ti'n waye.

O lede ọrọ naa nigba ti o'n ṣe ipade pẹlu awọn alẹnulọrọ ni ipinlẹ Taraba lọjọ aje.

Iroyin to tẹwa lọwọ lati oju opo twita Garba Shehu to jẹ agbẹnusọ fun aarẹ ni bakanna ni Buhari ṣe ipade pẹlu awọn lọbalọba ni ile ijọba Taraba lati wa wọrọkọ fi ṣ'ada lori ipaniyan to'n waye lagbegbe naa.

Image copyright @MBuhari
Àkọlé àwòrán Buhari bẹrẹ abẹwo ni Taraba lẹyin awuyewuye

Abẹwo rẹ si Taraba je akọkọ ninu eleyi ti o ti la kalẹ si awọn ipinlẹ ti ikọlu ti'n waye lorilẹẹde Naijiria.

Fayose: Abẹwo Buhari kii ṣe lati kẹdun

Ewẹ Gomina Ayodele Fayose ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ Aarẹ Buhari lati ṣe abẹwo si ipinlẹ Taraba.

O ni kii ṣe wi pe o fẹ ba awọn ara ipinlẹ naa kẹdun bi kii ṣe lati wa ibo wọn.

Atẹjade kan lati ọdọ agbẹnusọ rẹ, Lere Olayinka ni ''lẹyin igba ti Buhari da ọrọ naa wo ni o to o gbera lati lọ si awọn ipinle naa.''

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: