Ibo Italy: Ọmọ Naijiria di asofin agba ni Italy

Tony Iwobi Image copyright Iwobi facebook
Àkọlé àwòrán O le ni ọgbọn ọdun ti Tony Iwobi ti ngbe lorilẹede Italy

Ọmọ Naijiria kan to ti di ọmọ orilẹede Italy bayii, ẹni tii se agbẹnusọ fawọn atọunrinwa ninu ẹgbẹ oselu League, Tony Iwobi ni wọn ti dibo yan gẹgẹ bii asofin agba alawọ dudu akọkọ lorilẹede naa.

Tony iwobi, ẹniti wọn fẹsun kan ẹgbẹ oselu rẹ pe oun lo ru eefin iwa gbigbe oju agan sawọn ajeji soke nilẹ Italy, ni wọn dibo fun nilu Brescia tileesẹ nlanla pọ si julọ lẹkun ariwa orilẹede Italy, tawọn ajeji naa tun tẹdo si julọ.

Nigba to n fi itara sọrọ loju opo ikansiaẹni Facebook rẹ lori itakun agbaye, Iwobi ni "Pẹlu inu didun ni mo fi nsọ fun yin pe wọn ti yan mi gẹgẹ bii sẹnatọ. Igba ọtun si lo fẹ bẹrẹ yii."

Iwobi ti wọn bi nilu Gusau lorilẹede Naijiria, amọ to ngbe nilu Italy latọdun 1970 lo jẹ alatilẹyin nla fẹgbẹ oselu League lati bii ogun ọdun sẹyin.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Ọpọ igba si ni Iwobi ti maa npolongo pẹlu asaaju ẹgbẹ oselu naa, Matteo Salvini pe iwa kawọn ajeji maa wọ orilẹede Italy lọna aitọ ti mu ki iwa ẹlẹyamẹya pọ si lorilẹede naa.