Buhari: Maa ran Ghana lọwọ lati jagun iwa ijẹkujẹ

Aarẹ Muhammadu Buahri Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọpọ ogun ni Buhari gbe dide lati wa ọwọ iwa ijẹkujẹ bọlẹ ni Naijiria

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti safihan ifẹ rẹ lati fọwọsowọpọ pẹlu orilẹede Ghana lati gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede mejeeji.

Buhari sisọ loju ọrọ yii lasiko to nka ọrọ apilẹkọ rẹ gẹgẹbii alejo pataki nibi ayẹyẹ ọdun kọkanlelọgọta ti orilẹede Ghana gbominira eyi to waye nilu Accra.

Buhari tun gbosuba fun aarẹ orilẹede Ghana, Akufo-Ado fun aayan rẹ lati gbogun ti iwa ijẹkujẹ to ti di arun jẹjẹrẹ to jẹ tọrọ fọnkale.

"Mo ki ijọba atawọn asofin ku oriire lori bi wọn se tete fọwọsi ofin to wa fun agbekalẹ ọọfisi ti yoo maa ri si akanse igbẹjọ."

"Mo si fẹ sọ fun Ọlọla julọ pe o ni alabasisẹpọ ninu me nitori mo n foju sọna fun eto ajọsepọ lọna kọna laarin orilẹede Naijiria ati Ghana nidi wiwa egbo dẹkun fun arun ijẹkujẹ to ntan kalẹ kaakiri."

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

O fikun pe pẹlu agbekalẹ awọn ilana ofin yii, o da oun loju pe taa ba tun ni asaaju to tọ, ilẹ Afrika yoo tiraka lati le osi wọ igbẹ, ti eto isejọba alagbada yoo si maa rẹsẹ walẹ.