Osisẹ Jamb: Ọga mi lo mi 36m, kii se ejo

ejo
Àkọlé àwòrán Ohun abami ni kii ejo o maa jẹ owo

Ajọ to n gbogun tiwa jẹgudujẹra lorilẹede Naijiria, EFCC ti sọ wipe osisẹ Jamb to ni ejo gbe owo toto miliọnu mẹrindinlogoji naira to jẹ ti ajọ Jamb, Philomina Chieshe ti nkawọ pọnyin rojọ lori ẹsun irọ pipa ti ajọ Jamb fi kan an.

Losu to kọja, Philomina sọ wipe miliọnu mẹrindinlogoji naira ti wọn pa wọle nigba ti wọn ta kaadi fawọn akẹkọ to se idanwo Jamb fi n wo esi idanwo wọn lori ẹrọ ayelujara, ni ejo ma n wa sibi ti oun gbe owo naa pamọ si ninu ọọfisi oun lati rọọ owo yi mi.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Sugbọn iroyin fi ye ni wipe nigba ti arabinrin naa koju aajọ EFCC nibi iwadi ti wọn nse, o sọ wipe ọrọ naa ko ri bẹẹ mọ, ati wipe, ejo kọ lo gbe owo naa mi, sugbọn ọga oun lọọfisi, Samuel Sale Umoru, to jẹ adari ajọ Jamb ni Markurdi lo gba owo naa lọwọ oun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEjo abami to n mu owo ni ajọ Jambu

Lara awọn to kawọ pọnyin rọjọ lori owo kaadi Jamb ti wọn gba lọwọ awọn ọmọ ileewe ni Tanko Labaran lati ipinlẹ Nazarawa ati Yakubu Jakata ti ko tii salaye bi iye owo toto miliọnu lọna ogun naira se dawati nileesẹ Jamb to wa nipinlẹ Kano.