Akoroyin tawọn agbofin fi si ahamọ lorilẹede Naijiria gba itusilẹ

Awọn osisẹ ileesẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Lọjọọru ọsẹ to kọja ni ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS ransẹ peTony Ezimakor ti wọn si mu u si ahamọ

Awọn alasẹ orilẹede Naijiria ti tu oniroyin kan silẹ lẹyin ti wọn fi si ahamọ fun ọjọ meje.

Awọn alẹnulọrọ ati awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ gbogbo ni wọn pariwo sita lati ke si ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ apapọ orilẹede Naijiria, DSS wipe ko tu ọgbẹni Toni Ezimakor, akọroyin agba ni ọfiisi ileesẹ iroyin Independent Newspapers nilu Abuja ti wọn ti fi si ahamọ lati ọjọọru ọsẹ to kọja.

Lọjọọru ọsẹ to kọja ni ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ apapọ orilẹede Naijiria, DSS ransẹ pe ọgbẹni Tony Ezimakor, lati igbayii ni ẹnikẹni ko si ti rii.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Iroyin sọ wi pe awọn osisẹ ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ apapọ orilẹede Naijiria, DSS ya bo ọfiisi ati ilee rẹ ti wọn si ko awọn nkan kan lọ nibẹ.

Kilo fa mimu akọroyin, Tony Ezimakor?

Ohun ti awọn eeyan n sọ ni wi pe, mimu ti wọn mu akọroyin yii nii se pẹlu iroyin kan ti o kọ eleyii ti o pe akọlee rẹ ni "Chibok Girls: How Swiss-Mediated Deal Revived Boko Haram" (Itumọ eyi to ja si, Awọn ọmọbinrin Chibok: Bi idunadura ti orilẹede Swizerland se agbatẹru rẹ se tun se agbedide agbara Boko Haram).

Image copyright Tony Ezimakor
Àkọlé àwòrán Ibẹru bojo ti ba ọpọ awọn oniroyin lorilẹede Naijiria nitori ọkan o jọkan awọn ikọlu agbofinro nibẹ

O fẹ jọ bi ẹni wi pe iroyin naa fi awọn alagbara kan lorilẹede Nbaijiria siba-sibo, paapaa julọ bi o se jẹ wi pe ko pẹ pupọ ti awọn kọlọransi agbebọn Boko Haram yii tun ji awọn akẹkọ kan gbe ni ilu Dapchi ni ipinlẹ Yobe lẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria.

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ajafẹtọ ni awọn pinnu lati tubọ pariwo si eti ijọba pẹlu iwọde lowurọ ọjọọru kani ijọba o tu akọroyin naa silẹ ni.

Ohun ti oju awọn oniroyin n ri lorilẹede Naijiria

Fifi arakunrin yii si ahamọ ti ko ibẹru bojo ba ọpọ awọn oniroyin lorilẹede Naijiria.

Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ awọn ajafẹtọ ti pinnu lati tubọ se iwọde lowurọ ọjọọru kani ijọba o tu akọroyin naa silẹ

Lati ọdun 2015 ti ijọba Muhammadu Buhari to wa lode bayii lorilẹede Naijiria ti gori oye, ko din ni oniroyin marundinlogun ti wọn ti fi si ahamọ.

Oniruuru ikọlu lawọn oniroyin n doju kọ lẹnu isẹ wọn, ọpọ igba lo si jẹ wi pe wọn kii fi awọn agbofinro to lọwọ ninu ikọlu bẹẹ jofin.