Rex Tillerson: Amẹrika yoo ṣe'ranwọ owo tuntun fun Afirika

Minisita f'ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Amẹrika, Rex Tillerson Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọpọ n kọminu lori iroyin yii pẹlu bi Aarẹ Donald Trump kii se yee tẹnu mọọ wi pe ohun yoo din gbogbo owo ti orilẹede naa n na silẹ okeere ku

Ẹẹdẹgbẹta o le ọgbọn ati mẹta miliọnu dollar owo ilẹ Amẹrika ni orilẹede Amẹrika ti la kalẹ lati gbogun ti iyan lorilẹede South Sudan, Somalia, Ethiopia ati awọn agbegbe adagun omi Chad.

Eyi ni iroyin ti orilẹede Amẹrika fi sita bi minisita f'ọrọ ilẹ okeere nibẹ, ọgbẹni Rex Tillerson se n gbaradi lati se abẹwo akọkọ rẹ si ilẹ Afirika.

Minisita f'ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Amẹrika, Ọgbẹni Tillerson salaye wi pe ohun ti ohun n fẹ bayii ni ki awọn orilẹede yooku o gbọn ọwọ s'awo ikowojọ naa.

Ọgbẹni Tillerson ko sai kan sara si eto karakata orilẹede Amẹrika pẹlu ilẹ Afirika eleyi to ni o ti tubọ mu ki awọn karakata ti kii se ti oowo epo o burẹkẹ sii.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Amọsa, awọn onwoye kan ti n kun lori iroyin yii paapaa julọ anfani ti o sodo sinu rẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Rex Tillerson: Amẹrika yoo ṣe'ranwọ owo tuntun fun Afirika

Ọgbẹni David Amanor to ba John Stremalu, ẹni to jẹ ọjọgbọn ninu imọ niba ibasepọ ilẹ okeere lo sọ eyii.

Ohun ti o n kọ ọpọ lominu lori iroyin yii ko sẹyin bi aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump kii se yee tẹnu mọọ wi pe ohun yoo din gbogbo owo ti orilẹede naa n na silẹ okeere ku lati igba to ti de ori oye lọdun 2017.