Ipaniyan Benue: Isinku apapo yo waye fun ẹniyan mẹrinlelogun

Aworan Obinrin kan to ka'wọ lori Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ipaniya lẹnu ọjọ mẹta yi ni Benue ti sọ ọpọ sinu ibanujẹ

Iye ẹmi to ba iṣẹlẹ ipaniyan to waye ni ipinle Benue ti to mẹrinlelogun bayi.

Agbẹnusọ fun Gomina Ortom, Tahav Agerzua lo f'ọrọ naa lede.

O ni Gomina Ortom nigba ti ohun ati awọn ọmọ igbimọ eleto aabo ṣe abẹwo si Omusu Edimoga ni ijọba ibilẹ okpokwu sọ pe lọjọ ẹti lawọn yoo ṣe isinku apapọ fun awọn to padanu ẹmi wọn.

Ọjọ iṣẹgun ni Olofu Ogwuche, alaga ijọba ibilẹ Okpokwu ṣe afihan ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye fun Gomina Ortom.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Ogwuche sọ pe wahala bẹ silẹ nigbati awọn darandaran kan fẹjọ sun awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ pe awọn o ri maalu awọn mọ.

O ni bi wọn ti ṣe'n s'ọrọ naa lawọn gbọ pe awọn darandaran naa ti ya bo abule ti wọn si bẹrẹ sii nii pa awọn ẹniyan.

O ṣalaye pe laarin ago meji si mẹta lọjọ aje ni wọn wọ abule naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ipinle Benue ni ikolu to buru ju losu kini odun yi

Ẹwẹ, agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpa, Jimoh Moshood ti sọ fun BBC pidgin pe iroyin tuntun o tii tẹ awọn lọwọ lori isẹlẹ naa.