United Nations: Òní ni àyájọ́ ìfòpin sí ìdúkokò mọ́ àwọn akòròyìn lágbàáyé

Akoroyin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Àjọ Àgbáyé(UN) ní àwọn ẹgbẹ́ ajàfẹ́ẹ̀tọ́ kò ní dáké lórí ìdúkùkùlàjà mọ́ àwọn oníròyìn lágbàáyé.

Àjọ Ajafẹtọ ọmọniyan ninu Ajọ Isọkan Agbaye (UN) ti kesi awọn ipinlẹ lagbaaye lati ri i daju wi pe iwa ipa si awọn akọrọyin dopin lagbaye.

Ajọ UN ke gbajare naa lasiko ti wọn n se ayajọ jọ ifopin si idukoko ati ifiyajẹ awọn akoroyin ni agbaye.

Wọn fikun un wi pe ẹtọ ọmọniyan ni lati mọ ohun to n lọ lagbeegbe wọn, ti yoo si jẹ iroyin otitọ ti ko ni ẹẹbu ninu.

Awọn akọroyin to ba BBC sọrọ wi pe ọpọlọpọ igba ni awọn ti gba lẹta iku lẹnu isẹ nitori wi pe awọn fi iroyin to jẹ otitọ, amọ to tako ijọba to wa lode.

Ọkan lara awọn akọrọyin to jẹ obinrin ti a ko fẹ darukọ sọ iriri rẹ lasiko ti oun lọ se ifọrọwanilẹnuwo pẹlu dokita kan to gbajugbaja ni ilu Ibadan, ti o si fẹ ma fi ipa ba oun lopọ lẹyin ti oun se ifọrọwanilẹnuwo naa tan.

Àkọlé fídíò,

'Òṣìṣẹ́ Bánkì ni mí l'Amẹ́ríkà kí n tó bẹ̀rẹ̀ Tíátà'

Awọn akọroyin naa fikun wi pe ọpọlọpọ obinrin to jẹ akọroyin ni awọn eniyan ma n wo gẹgẹbi onisekuse ti wọn si ma n gbiyanju lati bawọn lopọ tipatipa.

Njẹ ominira wa fun awọn oniroyin ni Naijiria ?

Ṣe ki ṣe wi pe orilẹẹde Naijiria ti'n pada si igba inu fo aya fo ologun fun awọn onise iroyin?

Eyi ni ibeere ti awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ n bere lẹnu ọjọ mẹta yi ti itimọle awọn oniroyin peleke.

Àkọlé fídíò,

Pakistan: Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ wàhálà lórí ìdájọ́ arábìnrin tí wọ́n f'ẹ̀sùn ìsọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀sìn kàn

Lai pẹ yi ni ariwo po lori itimọle Tony Ezimakor, to je akọroyin agba ni ọfiisi ileesẹ iroyin Independent Newspapers nilu Abuja ti wọn fi si ahamọ fun ọjọ meje.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Tony Ezimakor

Àkọlé àwòrán,

Tony Ezimakor wa ni ahamo fun ọjọ meje ti awọn osisẹ ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ apapọ orilẹede Naijiria, DSS mu

Tony nikan ko

Oríṣun àwòrán, Facebook/Kayode Ajulo

Àkọlé àwòrán,

Afegbua ati awọn agbejoro re nigba ti wọn je ipe ile isẹ ọlọpaa

Agba ọje oniroyin,Kassim Afegbua je agbenuso fun Aare ana lorilẹẹde Naijiria,Ibrahim Babangida.

Atẹjade kan ti o fi sowo si awọn oniroyin loruko Bbabangida lo sokunfa wahala re pẹlu awọn ile ise olopa ti ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ apapọ orilẹede Naijiria, DSS naa si fiwe pe lati wa dahun si awọn ibeere.

Ẹyin o rẹyin ni awọn ọlọpaa tọrọ aforijin lọwọ rẹ sugbọn ko ti yanju ọrọ to so ohun ati DSS po.

Oríṣun àwòrán, Facebook/jAMIL iSMAIL mabai

Àkọlé àwòrán,

Jamil ko nipa owo ribiribi ti ijoba Katsina naa lori posi onirin

Lọjọ kejilelogun osu kẹsan ọdun 2017 ni ijọba ipinle Katsina so Jamilu sẹwon f'ọjọ mejilelogun lori ẹsun pe on k'ẹyin ara ilu si ijọba.

Oju opo facebook rẹ lo ko iroyin naa si eyi to mu ki awọn ẹka ọtẹlẹmuyẹ ile ise ọlọpaa ni Katsina wa mu ni Kaduna .

O ni ohun yi'n jẹjo niwaju adajo lori esun naa

Ipenija lo je fun wa

Oríṣun àwòrán, Facebook/Charles Okor

Àkọlé àwòrán,

Iroyin pe wọn mu oniroyin ki se iroyin to wuwa lati ko

Charles Okor to je Olootu agba iwe iroyin Daily Correspondent, ti wọn ti oniroyin re Tony Ezimakor mole ni bi ijoba ti se'n dun kukulaja mo awọn oniroyin ko le jẹki awọn yi ipinu pada.

'Ki se ohun to dun mọ wa ninu sugbọn eleyi ko le dawa lẹkun lati se isẹ wa bo ti se yẹ''

O ni ise ti awọn yan laayo ni ise iroyin ati wi pe gbogbo nnkan ti awọn ko lawọn le fọwọ sọya pe o je otito.

Igbiyanju wa lati ba Tony Ezimakor ti o sẹsẹ bo lọwọ ajo DSS soro ja si pabo.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ̀ si: