Asofin agba: A gbe ofin Peace Corps gba ẹyin Buhari

Ajọ Peace Corps to lọwọọwọ Image copyright PEACE CORPS WEBSITE
Àkọlé àwòrán Ajọ Peace Corps wa funawọn ọdọ lati pese aabo lorilẹede Naijiria

Ile igbimọ asofin lorilẹede Naijiria ti rọ aarẹ Muhammadu Buhari lati se atungbeyẹwo ero rẹ lati mase buwọlu abadofin to nse idasilẹ ajọ alalaafia,"Peace Corps of Nigeria".

Ile se ipinnu yii lẹyin ti Sẹnatọ Dino Melaye rọ ile asofin naa lati tun ọrọ naa gbeyewọ nigbati wọn n sepade.

Ninu ọrọ rẹ, Melaye rọ ile lati yẹ abadofin ọhun wo, pẹlu ileri wipe ti aarẹ Buhari ko ba buwọlu u, awọn yoo gba asẹ lati sọ abadofin naa di ofin, lai lọwọ aarẹ Buhari ninu.

Image copyright PEACE CORPS WEBSITE
Àkọlé àwòrán Senatọ Dino Melaye ni o pọn dandan ki aarẹ Buhari buwọlu Ajọ Peace Corps

Melaye sọ wipe ajọ naa wa fun awọn ọdọ ati wipe ọranyan ni lati gbe ọdọ orilẹede Naijiria larugẹ fun idagbasọke orilẹede wa.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Ti a ko ba gbagbe, aarẹ Buhari sọ wipe idi ti oun fi da aba naa nu ni wipe, ko si owo ninu apo asunwọn ijọba lati san owo osu fun ajọ naa, ati pe isẹ tawọn ẹlomii nse ni ajọ naa yoo tun maa se, nigba ti ajọ alaabo wa lati se isẹ ti wọn n se.