Iṣẹlẹ ado oloro: Chales Okah ati Nwabueze gba'dajọ ẹwọn gbere

Charles Okah
Àkọlé àwòrán Henry to jẹ ẹgbọn fun Charles Oklah ti gba idajọ ti ẹ lorilẹede South Africa lori isẹlẹ yii

Ileẹjọ giga ijọba apapọ to kalẹ silu Abuja ti ran Charles Okah ati akẹẹgbẹ rẹ ti wọn dijọ njẹjọ, Obi Nwabueze ni ẹwọn gbere.

Wọn gba idajọ naa lori bi wọn sese agbatẹru ado oloro to bu nilu Abuja lọjọ kinni osu kẹwa ọdun 2010 ati nilu Warri lọjọ kẹẹdogun osu kẹta ọdun 2010 kannaa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCharles Okah gba'dajọ ẹwọn gbere

Awọn meejeji yii ni wọn gbinmọpọ pẹlu ẹgbọn Charles, Henry Okah, tii se asaaju ẹgbẹ to nja fun ominira awọn eeyan Biafra tijọba ti fofin de, (Mend) ẹni toun naa ti gba idajọ tiẹ lori ẹsun yii saaju lorilẹede South Africa.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Nigba to ngbe idajọ rẹ kalẹ lori ẹjọ naa to ti bẹrẹ lati ọjọ keje osu kejila ọdun 2010, adajọ Gabriel Kọlawọle ni awọn olupẹjọ fi idi ẹri wọn mulẹ kọja iyemeji.

Idi si ree to fi da ẹwọn gbere fun wọn nibamu pẹlu ofin to ngbogun ti iwa sise owo ilu basubasu ati iwa ọdaran tsdun 2004, ori kẹẹdogun, ẹsẹ kinni ati ikeji.

Related Topics