Lush Beauties: Ẹ má jẹ́ k‘ójú tì yín torí pé ẹ sanra, ẹ jáde síta

Lush Beauties: Ẹ má jẹ́ k‘ójú tì yín torí pé ẹ sanra, ẹ jáde síta

Awọn ọmọ ẹgbẹ́ Lush Beauties, lasiko ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ ni, awọn to sanra maa n ni idojukọ gan ni, nitori pe ọpọ wọn ni kii wọ ọkọ elero abi ọkada nitori itiju, tawọn ọlọkọ yoo si ni ki wọn sanwo eeyan meji.

Amaka ati Jubi, ti wọn sọrọ lorukọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni, awọn da ẹgbẹ Lush Beauties silẹ lati jade se iwuri fawọn eeyan to sanra ni, ki wọn lee mọ pe ara sisan kii se arun, amọ ki wọn jade sita tori ko si ohun ti wọn ko lee se pẹlu ara sisan.

Bakan naa ni wọn rọ awọn eeyan to ba sanra ni ipinlẹ kọọkan, lati ko ara wọn jọ, bẹrẹ lati eeyan mẹwa, wa dara pọ mọ ẹgbẹ Lush Beauties.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ̀ si: