Saraki: Ilana gbigbogun ti iwa ijẹkujẹ ṣi n mẹhẹ lorilẹede Naijiria

Sẹnatọ Bukọla Saraki Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Ko to ida mẹwa awọn ileesẹ ijọba lorilẹ̀ede Naijiria to tẹle ofin isuna

Ileegbimọ aṣofin agba lorilẹede Naijiria ti pinnu bayii lati gbẹsẹ le iṣuna fun ileeṣẹ ati lajọlajọ ijọba apapọ bii oji lerinwo ati mẹrin fun kikuna lati tẹle ilana ti ofin orilẹede Naijiria gbe kalẹ fun ayẹwo iwe owo wọn ṣaaju ọjọ kejidinlogun ọdun 2018.

Igbesẹ yii n waye lẹyin ti o jẹyọ sita wi pe ninu ẹẹdẹgbẹta o din mẹsan awọn ileeṣẹ ati lajọlajọ to jẹ ti ijọba apapọ lorilẹede Naijiria, mẹtadinlaadọta pere lo tii tẹle ofin yii.

Alaga igbimọ to n ṣe kokaari iṣuna ilu nile aṣofin agba orilẹede Naijiria, Sẹnatọ Matthew Urhoghide ṣ'alaye eyi lasiko to fi n gbe abajade igbimọ naa kalẹ lori ibi ti ọrọ de duro lori bi awọn ileeṣẹ ijọba ṣe tẹlee ofin naa fun ayẹwo iwe inawo wọn.

Pupọ ninu awọn aṣofin agba to da si ọrọ naa ni gbagede ile ni wọn yanana rẹ wi pe iwa awọn ileeṣẹ ati lajọlajọ ti ọrọ kan ko lorukọ meji ju iwa ọdaran eleyi ti iwe ofin si la ijiya to tọ kalẹ fun.

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Awọn ileesẹ ti ko se ayẹwo iwe owo wọn ko lee ni ipin ninu isuna ọdun 2018

Kini ohun ti awọn aṣofin agba sọ?

Ninu ọrọ rẹ, Sẹnatọ Bala Na'allah ni 'o yẹ ka mọ boya ohun ti wọn ṣe yii ba ofin mu. Ohun to n ṣẹlẹ yii ṣe apẹẹrẹ aitọ ati aibojumu to gbilẹ si ẹka ilana iṣejọba wa. Mo roo wi pe ijiya kan naa lo yẹ ki a fi jẹ gbogbo wọn.'

Ninu ọrọ rẹ aarẹ ileegbimọ aṣofin agba lorilẹede Naijria, Sẹnatọ Bukọla Saraki ni abajade iwadi igbimọ ile naa ti fihan wipe orilẹede Naijiria ko ṣe aṣeyọri kankan ninu igbesẹ gbigbogun ti iwa ibajẹ.

"O ti han gbangba bayii wi pe ootọ ni ohun ti ile n sọ lọpọ igba wi pe a o ni itẹsiwaju kankan lori ọrọ gbigbogun ti iwa ibajẹ ati iṣowo ilu baṣubaṣu nitori awọn ipilẹ gbogbo to yẹ lati mojuto lo si mẹhẹ ti wọn si tun wọ.

Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Sẹnatọ Bukọla Saraki ni abajade iwadi igbimọ ile naa ti fihan wipe orilẹede Naijiria ko se aseyọri kankan ninu igbesẹ gbigbogun ti iwa ibajẹ

Ti a ba ri ileeṣẹ ijọba mẹtadinlaadọta pere to n tẹle ofin ninu mẹtadin lẹẹdẹgbẹta, mo ro wi pe iṣoro n la gba leyii. A si tun rii pe awọn ileeṣẹ wọnyii gan an lo yẹ ko maa ṣe atọna ati amojuto fun awọn ileeṣẹ yooku.

Aarẹ Ile aṣofin agba lorilẹede Naijiria ni awọn yoo fi afẹnuko wọn sọwọ si akọwe agba ijọba apapọ lati rii daju wi pe gbogbo awọn ileeṣẹ ijọba ati lajọlajọ yii ni wọn ṣe ayẹwo iwe owo wọn ki wọn si fi sọwọ.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ̀ si: