Awọn aṣofin f'ọwọsi Imam gẹgẹbi adajọ agba ile ẹjọ Sharia

Awoneeyan ti won gba idajo ile ejo Sharia kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Wọn fi ẹniọwọ Rufai Imam jẹ adele adajọ agba ilẹjọ kotẹmilọrun Sharia ni osu kẹta ọdun 2017

Ile asofin agba lorilẹede Naijiria ti buwọlu orukọ Ẹniọwọ Rufai Imam gẹgẹbii adajọ agba fun il ẹjọ kotẹmilọrun Sharia ni lu Abuja.

Lọjọọru ni awọn asofin agba buwọlu orukọ Ẹniọwọ Rufai Imam lẹyin ti igbimọ to n se kokaari ọrọ eto idajọ, ẹtọ ọmọniyan ati ọrọ ofin gbe orukọ rẹ kalẹ niwaju awọn asofin agba naa.

Nigba to n gba ero awọn asofin lori Ẹniọwọ Rufai Imam wọle, Aarẹ awọn asofin agba lorilẹede Naijiria, Sẹnatọ Bukọla Saraki ki Ẹniọwọ Rufai Imam ku oriire iyansipo rẹ pẹlu ikilọ wipe ko ṣe ohun to ba tọ pẹlu ipo rẹ lẹka iṣedajọ'

Ni oṣu kejila ọdun 2017 ni aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari fi orukọ Ẹniọwọ Rufai Imam ṣọwọ si ile asofin agba fun ifọwọsi wọn gẹgẹbii adajọ agba ileẹjọ Sharia ni olu ilu orilẹede Naijiria, Abuja.

Saaju ifọwọ si yii, Aarẹ Buhari ti kọkọ kede orukọ Ẹniọwọ Rufai Imam, gẹgẹbii adele adajọ agba ilẹjọ naa ni ọjọ kẹrindinlogun osu kẹta ọdun 2017 lẹyin ti ẹni to di ipo naa mu tẹlẹ ti fẹyinti.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ̀ si:

Related Topics